Ìdíje Chelsea: Ọ̀mì ayò dákún ìsòro rẹ̀

Aworan Javier Hernandez

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Goolu ti Javier Hernandez je dakun isoro Chelsea ni saa league ọdun yi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Nnkan ko sẹnu re fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea pẹlu bi wọn ti se gba ọmi ayo 1-1 pẹlu West Ham lopin osẹ.

Ni saa bọọlu ọdun yi, kaka ko mi san lara iya ajẹ́ ni ọrọ chelsea, amọ to n fi gbogbo ọmọ rẹ bi obinrin, ti ẹyẹ wa n yi lu ẹyẹ gbaa, nitori, ọpọ ipenija ni ẹgbẹ naa koju, to si dabi wi pe, ẹni to ti mọọ se ri, ko fẹ mọọ se mọ.

Lọjọ ti wọn se iranti gbajugbaja ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu naa nigba kan ri, Ray Wilkins to dologbe, Chelsea kọ lati bori West Ham.

Olukọni ẹgbẹ naa, Antonio Conte ni, gbogbo awọn lawọn jo lẹbi aisedede naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ọmi ti wọn gba ninu ifẹsẹwọnsẹse naa se okunfa bi West Ham ti se ja kuro lagbami ijakule pẹlu ami mẹfa sugbọn bi nnkan ti se ri, ko daju pe wọn yoo le kopa ninu Champions League lọdun to n bọ.