Conte: Ipo kẹrin ko lee rọgbọ fun Chelsea

Olukọni fun ikọ agbabọọlu Chelsea, Antonio Conte

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lati ipo asiwaju si ipo karun ni irinajo Chelsea j ninu atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi

Olukọni agbabọọlu Chelsea, Antonio Conte ti sọ wipe yoo nira diẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu naa lati gbe ori wọ aarin awọn ẹgbẹ agbabọọlu mẹrin akọkọ ninu atẹ igbelewọn liigi premiership ti ilẹ Gẹẹsi.

Conte s'ọrọ yii lẹyin ti ikọ rẹ padanu ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu ikọ agbabọọlu Manchester United ni papa iṣere Old Trafford.

"Iṣẹ nla ni o. A ni lati fi gbogbo ọkan wa jinki, a si mọ afojusun pataki ti o n bẹ niwaju wa.

"Ko dẹrun lati kogoja fun idije Champions league ni liigi yii"

Antonio Conte gbe ife ẹyẹ liigi ilẹ Gẹẹsi dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Osu karun ọdun 2017 ni Chelsea gba ife liigi ilẹ Gẹẹsi

Willian lo kọkọ ṣide goolu ninu ifẹsẹwọnsẹ naa ki Romelu Lukaku ati Jesse Lingard to mi awọn fun Manchester United eyi lo si da Manchester United pada si ipo keji lori atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi. Manchester City ni Chelsea yoo ma ba waako ni ọjọ aiku to n bọ.

Bakanna ni ikọ Chelsea si wa ninu idije Champions league ti wọn si ti ta ọmi pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona ni abala akọkọ ipele komẹsẹ-o-yọ akọkọ fun idije naa fun saa ọdun 2018.

Oludari ifẹsẹwọnsẹ naa kuna lati gba goolu kan ti agbabọọlu Chelsea, Alvaro Morata, gba wọle lori ẹsun pe o ti kọja aaye rẹ (offside).

Lori eyi, Conte ni asiko to lati bẹrẹ lilo irinṣẹ fidio aṣeranwọ fun oludari ifẹsẹwọnsẹ bọọlu (VAR) ni ilẹ gẹẹsi.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: