Bolt tọwọbọwe adehun pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu kan

Usain Bolt

Oríṣun àwòrán, Gallo Images

Àkọlé àwòrán, Usain Bolt ti si oju kuro nidi ere sisa si ere bọọlu afẹsegba
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Gbajugbaja elere ori papa, Usain Bolt sọ pe oun ti tọwọbọwe adehun lati darapọmọ ẹgbẹ agbabọọlu kan.

Lori oju opo facebook rẹ lo ti kede ọrọ naa.

Ṣugbon o kọ lati darukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa.

O ni ki ẹnikẹni to ba fẹ ẹ mọ orukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa pade oun lọjọ iṣẹgun.

Awọn ololufẹ rẹ ti bẹrẹ si nii daba orukọ ẹgbẹ ti wọn lero wi pe o le jẹ

Usain Bolt pelu Pitso Mosimane ati Hlompho Kekana ni Mamelodi Sundowns

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mamelodi Sundowns figbakan gbalejo Usain Bolt

Laipe yi ni aworan Usain Bolt gba ori ẹrọ ayelujara nibi ti o ti'n ṣe igbaradi pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Mamelodi Sundowns ni orilẹẹde South Africa.

Ọdun 2017 ni Bolt fẹyin ti nibi ere ori papa.

Awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: