Usain Bolt: Bọọlu gbigba lo kan fun mi

Gbajugbaja Asaregbayi nni, Usain Bolt

Oríṣun àwòrán, @Masandawana

Àkọlé àwòrán, Gbajugbaja Asaregbayi nni, Usain Bolt ti gbe oju kuro lara ere sisa lọ sidi ere bọọlu alafẹsẹgba

Ikọ agbabọọlu Mamelodi sundowns nilẹ South Africa ti gba alejo nla bayii pẹlu bi etu obeje ẹlẹsẹ ere, to jẹ ọmọ ilẹ Jamaica nni, Usain Bolt, se ti gunlẹ si agbo ikọ naa fun igbaradi ere bọọlu lọjọ aje.

Gbajugba elere ori papa ọmọ ilẹ Jamaica naa, se igbaradi pẹlu awọn agbabọọlu Mamelodi to si tun la wọn lọyẹ lori awọn ọna abuja si ere sisa.

Usain Bolt ati awọn agbabọọlu ikọ Mamelodi Sundowns lasiko igbaradi wọn

Oríṣun àwòrán, @Masandawana

Àkọlé àwòrán, Ami nla ni ifarahan Usain bolt ninu ikọ Mamelodi Sundowns jẹ fun idagbasoke ere bọọlu alafẹsẹgba nilẹ Afirika

Onigbọwọ kan naa lo nse agbatẹru asaregbayi Bolt ati ikọ agbabọọlu Mamelodi Sundowns, to si jẹ wipe, laifọtape, awọn mejeeji yii lo ti tayọ ninu ohun ti wọn yan laayo.

Ami ẹyẹ goolu mẹjọ ni Usain bolt ti gba bọ wa sile lati idije ere idaraya Olympic, eyi to fẹẹ se kongẹ afojusun awọn ikọ Mamelodi, tawọn naa nlepa ami ẹyẹ liigi kẹjọ nilẹ South Africa.

Usain Bolt n sọrọ ni ibudo igbaradi Mamelodi Sundowns

Oríṣun àwòrán, @Masandawana

Àkọlé àwòrán, Usain Bolt yoo maa gbaradi pẹlu ikọ Mamelodi Sundowns titi di osu kẹta ọdun

"Odu ni ikọ agbabọọlu Mamelodi, inu mi si dun pupọ lati bawọn dowo pọ. Lootọ, mi o lee sọ bi mo ti se yara si pẹlu bọọlu sugbọn bo pẹ, bo ya, emi naa maa de oju iwọn lẹnu rẹ."

Usain Bolt ni, sise igbaradi pẹlu ikọ Mamelodi sundowns ti si oun loju lati rii pe ere ori igi nikan ni ẹdun oun lee saa, ati pe omi nbẹ laamu fun oun lori ọrọ ati gba bọọlu jẹun.

Usain Bolt atawọn agbabọọlu Mamelodi Sundown

Oríṣun àwòrán, @Masandawana

Àkọlé àwòrán, Ireti awọn agbabọọlu Mamelodi Sundowns ni pe Usain Bolt lee tọwọ bọ iwe adehun pẹlu ikọ agbabọọlu naa.

"Maa sa gbogbo ipa lati rii daju pe ara mi tete bọ sipo ki n lee dara pọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Borrusia Dortmund ni osu kẹta ọdun.

Ninu ọrọ rẹ, agbabọọlu ikọ Mamelodi Sundowns kan, Percy Tau ni, iriri nlanla lo jẹ fun asaregbayi ọmọ ilẹ Jamaica naa lati darapọ mọ awọn.