Ko daju wipe Neymar le kopa ninu idije Champions League

Oríṣun àwòrán, EPA
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
O ṣeeṣe ki agbabọọlu ti owo ori rẹ pọju lagbaye, Neymar, ma kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ẹgbẹ rẹ, PSG pẹlu Real Madrid ninu idije Champions League.
Eyi ko ṣẹyin bi o ti ṣe fi kokosẹ rẹ rọ ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye lọjọ aiku pẹlu Marseille.
Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ n ṣe adura ki ara rẹ da ki o to di ọjọ isẹgun.
Ṣaaju nibi ifẹsẹwọnsẹ wọn ninu idije Champions League, Real Madrid fagbahan ẹgbẹ agbabọọlu PSG pẹlu ayo mẹta si ọkan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Cristiano Ronaldo ati Marcelo wa lara awọn ti wọn gba bọọlu wọle fun Real Madrid nibi ifẹsẹwọnsẹ naa.
Oku ki Neymar ṣ'ara giri lati le kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ pataki eleyi ti yoo waye lọjọ isẹgun.








