Chelsea lè yọ Antonio Conte gẹ́gẹ́bí akọ̀nimọ̀ọ́gbà

Lẹ́yìn tí Tottenham sán bàǹtẹ́ ìyà fún Chelsea ní Stamford Bridge, Antonio Conte wípé òun kò bẹ̀rù kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ òun.

Antonio Conte

Oríṣun àwòrán, AFP/GETTY

Àkọlé àwòrán, Ọjọ́ iwájú akọnimọ̀ọ̀gba Chelsea Antonio Conte ni Stamford Bridge kò dájú. Ṣùgbọ́n tani ó lè gbà ipò rẹ̀?
Mauricio Pochettino

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Mauricio Pochettino ni akọ̀nimọ̀ọ́gbà fún Tottenham. Òun ló na Chelsea pẹ̀lu àmì ayò mẹ́ta lọ́jọ́ àìkú. Ìròyìn wípé Roman Abramovic ń ronú nípa rẹ̀.
Massimillano Allegri

Oríṣun àwòrán, AFP/GETTY IMAGES

Àkọlé àwòrán, Akọ̀nimọ̀ọ́gbà fún Juventus, Massimillano Allegri ti gba ife ẹ̀yẹ Seria A ní italy ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé tí ó sì ti gbá ìdíje àṣekágbá Champions League lẹ́ẹ̀mejì.
Roberto Mancini

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Roberto Mancini jẹ akọ̀nimọ̀ọ́gbà tó ní ìrírí premier league lẹ́yìn tó gba ife ẹ̀yẹ naa ni 2011/12 fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Manchester City.
Luis Enrique

Oríṣun àwòrán, AFP/GETTY IMAGES

Àkọlé àwòrán, Luis Enrique jẹ akọ̀nimọ̀ọ́gbà fún Barcelona tẹ́lẹ̀rì, tó sì gba ife ẹ̀yẹ mẹ́ta fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù rẹ̀ láàárín sáà kan ṣoṣo.
Thomas Tuchel

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Thomas Tuchel, tó jẹ́ akọ̀nimọ̀ọ́gbà tẹ́lẹ̀rì fún Borussia Dortmund, ni àwọn ènìyàn ńrò wípé ó ṣeése kí o gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Conte. Tuchel sọ fún Bayern Munich wípé òun kò fẹ́ẹ́ kọ́ won.