Buhari orders ministers to resign: Kìí ṣe àwọn mínísítà tó fẹ́ dupò nìkan ní Buhari ní kó fi iṣẹ́ sílẹ̀ , wo àwọn tó tún kàn

Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun gbogbo awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ rẹ to fẹ dupo oṣelu lati fa akoso le ẹni to jẹ igbakeji wọn lọwọ.

Ikede tuntun yii waye ninu atẹjade kan ti akọwe ijọba apapaọ, Boss Mustapha fi sita ni owurọ Ọjọbọ.

Ọjọru ni Aarẹ Buhari kede, lati ẹnu minisita fun eto iroyin, Lai Muhammed, pe ki gbogbo awọn minsiita fo fẹ lọ dije fun ibo ọdun 2023 kọwe fi ipo wọn silẹ titi ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un.

Ninu ikede ti Mustapha fi sita, o ni aṣẹ naa tun kan awọn aṣoju Naijiria nilẹ okeere, awọn olori ileeṣẹ ati ajọ to jẹ ti ijọba, to fi mọ awọn mii ti ijọba yan sipo gẹgẹ bi oloṣelu.

"Gbogbo awọn minisita ti aṣẹ yii kan, gbọdọ fa akoso ileeṣẹ ti wọn n mojuto le minisita keji lọwọ, tabi akọwe agba, nibi ti ko ba ti si minisita keji.

"Awọn to jẹ aṣoju orilẹ-ede gbọdọ fa akoso le igbakeji wọn tabi oṣisẹ to ga ju lọ lọwọ."

Fun awọn to wa ni awọn ajọ ati ileeṣẹ ijọba mii, wọn gbọdọ fa iṣẹ le oludari agba to wa ni ẹka wọn lọwọ.

Boss Mustapha sọ pe ni kiakia ni aṣẹ naa fidi mulẹ.

Buhari pàṣẹ fún àwọn mínísítà tó bá fẹ́ dupò òṣèlú láti kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ ní kíá

Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun gbogbo awọn minsita rẹ lati kọwe fi ipo wọn silẹ ti yoo ba fi di ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un.

Minisita fun eto iroyin, Lai Mohammed lo kede aṣẹ naa lẹyin ti wọn pari ipade igbimọ alaṣẹ Niajiria to waye nile ijọba nilu Abuja.

Awọn minisita ti ọrọ naa kan ni Rotimi amaechi, minisita fun eto irinna; Chris Ngige, minisita fun ọrọ oṣiṣẹ; Abubakar Malami, minisita fun eto idajọ; ati Godswill akpabio, minisita fun ọrọ Niger Delta.

Gbogbo awọn minisita yii lo ti fi erongba wọn han pe awọn fẹ dije fun boya ipo gomina, sẹnetọ tabi aarẹ.

Awọn yooku ni Uche Ogar, minisita keji fun iwakusa; Pauline Tallen, minisita fun ọrọ awọn obinrin.

Ṣaaju, ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2022, ni Aarẹ Buhari kesi ile aṣofin agba, lati ṣe atunsẹ si abala kẹrinlelọgọrin ofin , eyi to fi ofin de pe ẹni to ba di ipo osẹlu mu ko gbọdọ dije fun ipo.

Ṣugbọn awọn aṣofin ko ṣe bẹẹ si ofin to ni iru ẹni naa gbọdọ kọkọ kọwe fi iṣẹ silẹ ni ipo rẹ, ko to le dije.

Koda, ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu abuja paṣẹ pe Buhari, minisita fun eto idajọ, abubakar Malami, ati awn aṣofin, ko gbọdọ yi ofin naa àda rara.

Ọjọ Iṣẹgun ni ile aṣofin agba buwọlu ofin kan pe igbakeji aarẹ, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin, gomina atawọn igbakeji wọn, awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ, awọn alaga kansu, kansilọ atawọn ọmọ igbimọamuṣẹya ẹgbẹ oṣelu gbogbo, le dupo osẹlu lai fi ipo ti wọn wa silẹ.