2023 Election: Femi Falana ní òfin kò faàyè gba kí Goodluck Jonathan dupò Ààrẹ

Ìdí nìyí tí Jonathan kò fi le díje dupò Ààrẹ Nàìjíríà mọ́

Leyin ti awọn fulani darndaran kan ra fọọmu fun Goodluck Jonathan lati dije dupo aarẹ Naijiria ni awọn eeyan tun ti n beere pe ṣe o lẹtọ lati dije dupo labẹ asia ẹgbẹ APC ni.Èmi ò gbé'ṣẹ́ rán ẹnikẹ́ni láti ra fọ́ọ̀mù ìdíje ààrẹ fún mi o, ẹ máà kóbá mi -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Jonathan fún Miyetti Allah lésì

Ni kete ti iroyin naa milẹ titi tan ni Goodluck jade sọ pe oun ko fẹ fọọmu idije dupo aarẹ naa.

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ laarin Goodluck ati Falana?

Gbajúgbajà agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Femi Falana ti sọ wí pé Ààrẹ àná orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Goodluck Jonathan kò le díje dupò Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí mọ́.

Falana nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, ọdún 2022 ní lábẹ́ òfin Jonathan kò le dupò Ààrẹ mọ́ lábẹ́ òfin.

Ó ní wí pé abala kẹtàdínlógójé ìwé òfin orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti là á kalẹ̀ wí pé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá ti búra wọlé fún gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ láti parí sáà Ààrẹ ẹlòmíràn, kò le ṣe ju sáà kan lọ.

Ohun tí ó ṣokùnfà ọ̀rọ̀ yìí ni bí awuyewuye ṣe ń lọ lórí pé Ààrẹ àná Goodluck Jonathan yóò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) láti dúpò Ààrẹ.

Ó ní ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá mú Jonathan gẹ́gẹ́ bí olùdíje ni ó ṣeéṣe kí wọ́n kojú ìjákulẹ̀ nílé ẹjọ́.

Ẹgbẹ́ àwọn ìdàgbàsókè Igbo ní àwọn yóò wọ Jonathan lọ sí ilé ẹjọ́

Bákan náà ni igbákejì alága ẹgbẹ́ ìdàgbàsókè àwọn ẹ̀yà Igbo, Dókítà Law Mefor ní àwọn yóò gbé Jonathan lọ sí ilé ẹjọ́ tí ó bá fi lè kéde wí pé òun fẹ́ dupò Ààrẹ.

Mefor ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun gbàgbọ́ wí pé ẹkùn gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀ èdè yìí ló yẹ kí Ààrẹ ti wá lọ́dún 2023, ó ní ìwé òfin orílẹ̀ èdè yìí kò fàyè gba kí Jonathan gbégbá ìbò mọ́.

Ẹ ó rántí pé ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Jonathan ní òun ń kàn sí àwọn ènìyàn òun lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá òun yóò gbégbá ìbò lọ́dún 2023.

Bákan náà ni àwọn àhèsọ ọ̀rọ̀ kan ti ń lọ wí pé Jonathan ti ń fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC gbèdéke wí pé tí òun yóò bá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú náà, wọ́n gbọ́dọ̀ fi òun ṣe olùdíje ipò Ààrẹ.