1999 Constitution case: Adájọ́ sún ìgbẹ́jọ́ ẹjọ́ INEC àti Ilana Oodua ni Ado Ekiti lórí ìwé òfin Nàìjíríà 1999 síwájú

Lẹ́yìn o reyin ni ile ẹjọ giga ni Ado Ekiti ni Adajọ ti sun ẹjọ naa siwaju.

Saaju ni Ilana ọmọ Oodua to n ja fun ominira iran Yoruba kuro ni Naijiria ti gbe ajọ eleto idibo Ńaijiria, INEC lọ sile ẹjọ.

Igbejo naa waye lori koko pe ki eto idibo ma se waye ni ipinlẹ Ekiti laisi atunse si iwe ofin Naijiria ti ọdun 199 ti a n lo lọwọ ti wọn ni o kun fun kò tọ́.A kọ̀ láti yí ọkàn wà padà lórí ìpinnu Yorùbá Nation- Ilana Omo Oodua

Kini abajade nile ẹjọ́?

Lẹyin atotonu iko mejeeji ni Adajọ sọrọsoke.

Adajọ Agba Babs Kuewunmi ti ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa ni ilu Ado Ekiti ti sun ẹjọ naa siwaju

Ejo naa ti ẹgbẹ Ọmọ Ilana Oodua gbe lo ile-ejo siwaju di ọjọ kọkanla oṣu karun-un, lori pe ko ní sí ibo gomina ni ipinle Ekiti, Osun ati lọdun 2023, Lai sí iwe ofin tuntun àti atunto orilẹ-ede Naijiria.

Awọn Ẹgbẹ ilana ọmọ Oodua ni wọn gbé agbefoba agba ati àjọ INEC lo sí ilè ejo lori eto idibo to n bo l'ekiti.

Kini o tun ṣẹlẹ nile ẹjọ?

Awọn oludahun ninu ẹjọ naa, agbẹjọro agba fun agbefoba agba ati ajọ eleto idibo orilẹ-ede ni kò sí ni kootu fún ẹjo naa.

Agbẹjọro fún àwọn olugbejo ilana ọmọ Oodua, agbẹjọro Tolu Babayemi sọ pé àwọn mu iwe ipejo lọ fún àjọ INEC ati Agbefoba àgbà (Anthony General).

Sugbon awon o mo idi ti won ko sí ilè ẹjọ loni, ti ọ sí tun sọ pe awọn yo tun lọ fún wọn ní ìwé miran lati fi ran won leti.

Adajọ Agba Babs Kuewunmi ti ile ẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa ni ilu Ado Ekiti ti sun ẹjọ náà siwaju sí ọjọ kọkanla oṣu karun-un.

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ?

Ìgbẹ́jọ́ Ilànà Ọmọ oodua àti Náìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ ní Ekiti

Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, ni pe ko ní sí ibo lọdun 2023, Lai sí iwe ofin tuntun àti atunto orilẹ-ede Naijiria ti wọn sì ti gbé àjọ INEC lo sí ilè ejo.

Àwọn aṣáájú ẹgbẹ Ilana Omo Oodua ti gbe INEC wa sí ile ejo ìjọba àpapọ̀ ti o wá ni ilu Ado-Ekiti lati da wọn lowo duro lati ma se ètò idibo gomina ni ipinle Ekiti ati Osun.

Ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua ni eto idibo lati beere lọwọ awọn ọmọ Naijiria Iori bo ya won sì fẹ tẹsiwaju gẹgẹ bí orilẹ-ede kan gbọdọ wáyé ṣáájú ibo ọdún 2023.

Opolopo igba ni ẹgbẹ ọmọ Ilana Oodua pé iwe òfin ọdun 1999 ni jìbìtì, pé láìsí ìwé òfin tuntun, Yorùbá ń lọ.

Ẹgbẹ naa ni ohun ko ni fi iwa-ipa da awọn Olùdìbò duro, sugbon oun yoo lo agbara ti ofin ati awọn kootu, ni ibamu pẹlu ipinnu ati eto imulo ti a mọ daradara.

Gbogbo bi o ba se lo ni ile ẹjọ apapo ni Ado-Ekiti ni ikanni BBC news Yoruba o ma mu wa sí etí igbó ati ojú iworan yin.