You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Alaafin's burial: Òní ni ọjọ́ mẹ́jọ ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi ni ìlú Oyo
A-gbọ́-'sá!-sá!!'-má-sàá.
Babaa Babátúndé,
A-gbọ́-'yà!-yà!!'-má-yà.
Àtàndá, babaa Kúdí
Tíí gbọ́ kurúù má mira.
Láyíwọlá, ọba lọmọọ Láwọin.
Kábíèsí Aláàfin.
Àjẹ́-kùnrin
Abẹ-lórí-eékán;
Àjẹ́-kùnrin
A-bi-làbẹlàbẹ-ìjà-layà.
Diẹ lara oriki Oba Lamidi Adeyemi to darapọ mọ awọn Alaseku ree.
Ojo ketalelogun, osu kẹrin, ọdun 2022 ni Oba Atanda Olayiwola Adeyemi waja.Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
- Ẹ yé fi ìpapòdà àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ Oyo kọmi lọ́rùn - Gómìnà Seyi Makinde
- Wo àwọn òrékelẹ́wà tí yóò ṣe opó lẹ́yìn Aláàfin Oba Adeyemi tó papòdà
- Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà
- 'Aláàfin ti rí ikú rẹ̀ ṣáájú ọjọ́ tó wàjà, ó sọ̀rọ̀ sílẹ̀ kó tó kú'
- Àṣírí ńlá tó ń bẹ láàrín Alaafin àtàwọn onílù rẹ̀ rèé
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
Leyin ti ara Oba Lamidi Adeyemi wo kaa ile tan ni wọn ṣe Orò Ije fun Alaafin Oyo to jọba fun odun mejilelaadota ki o to terigbaṣọ.
Oba Lamidi Adeyemi yato ninu awọn Oba Alade ilẹ̀ Yoruba ni gbogbo ọnaIrú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
Ojọ Abamẹta Oni, ọgbọn ọjọ, oṣu kérin ọdun 2022 ni wọn yoo ṣeto ayẹyẹ ọjọ mẹjọ iranti ipapoda Oba Lamidi Adeyemi ni Oyo.
- Wo bí ètò Orò Ìje Oba Lamidi Adeyemi to wàjà ṣe lọ ní Oyo
- A ti yọwọ́ olùdíje méji kúrò láwo lẹ̀yìn àyẹ̀wò, wọn kò lè díje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ PDP- David Mark
- Kí lo mọ̀ nípa ìgbeyàwó Àbẹ̀ẹ́lẹ̀, Àṣàǹte, Ọkọ Káalẹ́ àti Gbàmí o ràmí?
- Báyìí ni Egúngún àti Orò ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba
- Mo sọ kẹ̀kẹ́ mi dí ọ́kadà pẹ̀lú N35, 0000 tí mó ná sìí- Adewole ọmọ ọdún 16
- Àjákálẹ̀ àrùn tuntun tí ayé ń sọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ rèé...
- Tí mo ba ti múra bí ọkùnrin fi kọrin, kò sí ọ̀dọ̀ ààrẹ́ tí mi ò lè wọ̀- Erelu, ọmọ Elemure Ogunyemi
- Bíbéli mi ló sọ pé kí n fẹ́ ìyàwó omidan márùn ún, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀- Pásítọ̀
Aago mọkanla ni gbogbo eto yoo bẹrẹ ni Aafin Oyo.
Yoruba ni ori ti yoo dade, ko ni ṣe alai dade, ọrun ti yoo si lo ejigbara ilẹkẹ, ko ni ṣalai lo ó, ibadi ti yoo lo mọsaji, aṣọ ọba to jinna koro koro, ko kuku ni ṣe alai lo.
Bẹẹ ni ọrọ Ọba Lamidi Olayiwola Adeyemi kẹta rí,ẹni ti ori gbe de ipo awọn baba rẹ leyin ọpọ ifigagbaga laarin awọn ọmọ oye to le ni mẹwa, ti wọn dìjọ du ipo.
Ọjọ nla si ni ọjọ Kẹrinla osu Kinni ọdun 1971 ti atọbatẹlẹ ko to jọba, Lamidi Atanda Olayiwola Adeyemi gori itẹ awọn baba nla rẹ.