Public Holiday Ramadan: Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ méjì fún àyájọ́ òṣìṣẹ́ àti ìtúnu aàwẹ̀ Ramadan

Ìjọba àpapọ̀ ti kéde ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejì àti ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ kẹta oṣù Karùn-ún, ọdún 2022 fún ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti ṣàmì ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ àti ọdún ìtúnu àwẹ̀.

Mínísítà fọ́rọ̀ abẹ́lé, Ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbesola ló kéde èyí fún ìjọba àpapọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan.

Aregbesola, nígbà tó ń kí àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà kú ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́, kan sáárá sí àwọn òṣìṣẹ́ fún akitiyan àti ìlàkàkà wọn.

Ó ní ipa àwọn òṣìṣẹ́ kò ṣé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn rárá nítorí àwọn ni okùnfà àti ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ìdàgbàsókè àwùjọ ni wọ́n jẹ́.

Bákan náà ló pàrọwà sí àwọn òṣìṣẹ́ láti túnbọ̀ máa tẹpá mọ́ṣẹ́, kí wọ́n sì máa sa ipá wọn láti ri wí pé gbogbo ìfọkàntán tí ìjọba ní nínú wọn, wọn kò ja kulẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló wòye wí pé àwọn òṣìṣẹ́ nílò láti ní àfojúsùn tó gbópọn nítorí àti lè wà ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ takuntakun tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ń gbé ṣé àti pé kí ìrúgọ́gọ́ le bá owó tó ń wọlé lábẹ́nú fún Nàìjíríà.

Aregbesola kan sáárá àwọn Mùsùlùmí lórí ọdún ìtúnu àwẹ̀

Aregbesola tún kí àwọn Mùsùlùmí kú ìparí àwẹ̀ Ramadan, tó sì rọ̀ wọ́n pé gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ ìfẹ́, ìforítì, àláfíà, ìfarajìn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n kọ́ nínú àwẹ̀ Ramadan ni wọ́n ń ṣàmúlò lẹ́yìn àwẹ̀.

Mínísítà náà ní ó pọn dandan kí àwọn Mùsùlùmí máa là kàkà láti máa tẹ̀lẹ́ gbogbo àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà Ànọ́bì Muhammad kí ìfẹ́ àti ìrẹ́pọ̀ lé jọba láwùjọ.

Aregbesola fi kun un pé òun gbàgbọ́ wí pé gbogbo ìpeníjà ètò ààbò tí àwọn apá ibì kan ń kojú ní orílẹ̀ èdè yìí ni yóò di ohun ìgbàgbé láìpẹ́.

Ó ni ìjọba ń ṣe akitiyan tí wọ́n sì ń fi gbogbo ohun èlò tó yẹ lélẹ̀ láti ri dájú pé àláfíà àti ìṣọ̀kan Nàìjíríà dúró ṣinṣin.

Bákan náà ló sọ àrídájú rẹ̀ wí pé Ààrẹ Muhammadu Buhari ní ìfarajín sí ríri dájú pé ààbò tó péye wà fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Bẹ́ẹ̀ náà ló kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ń ṣe lórí gbígbé ogun ti ìwà ọ̀daràn àti dídá àláfíà padà sí àwọn àyè kan ní orílẹ̀ èdè yìí.