Indonesia ban export of palm oil: Ọ̀nà wo ni ìgbésẹ̀ yìí yóò fi ni ipa lára Naijiria àti Africa lápapọ̀?

Orilẹ-ede Indonesia ti fi ofin de tita epo pupa lọ si awọn orilẹ-ede miran.

Indonesia, to wa ni Gusu Asia, lo n pese ìpín to ju ilaji lọ ninu gbogbo epo pupa ti wọn n lo ni agbaye.

Nkan to fa igbesẹ tuntun yii ko ṣẹyin bi awọn ọmọ orilẹ-ede Indonesia ṣe bẹrẹ iwọde tako bi owo epo pupa ṣe wọn lọdọ wọn.

Ọwọ gogo naa n waye nitori bi awọn olokoowo ṣe n ko eyi to pọ ninu epo naa lọ si awọn orilẹ-ede miran.

Ibeere to gba ọkan gbogbo eeyan ni pe, nibo ni ilẹ Africa, to n ra epo pupa ju, yoo ti ma a ri epo ra bayii?

Lọdun 2021 nikan, biliọnu marun-un Dọla ni Africa na lati ra 'metric tonnes' epo pupa, lati Indonesia ati Malaysia.

Nilu Kuala Lumpur, olu ilu Malaysia, $1,850, ni wọn n ta toonu epo kan.

Laarin $150 si $200 si ni wọn fi n gbe tọọnu kan.

Eyi tumọ si pe bi ẹgbẹrun meji Dọla ni tọnu epo kan n ba de Africa.

Ṣe na abayọ wa fun awọn orilẹ-ede to n ra epo ju lati ilẹ okeere?

Fun awọn orilẹ-ede bi India, Bangladesh ati Pakistan, o ṣe e ṣe ki wọn o bẹrẹ si ra epo pupa wọn ni Malaysia.

Ṣugbọn ko daju pe Malaysia to jẹ oril-ede keji to n ta epo pupa ju l'agbaye, ma le pese gbogbo nkan ti wọn n fẹ, nitori ọwọn oṣiṣẹ.

Indonesia lo n pese bi ilaji epo pupa ti wọn n lo ni India.

Ti Pakistan ati Bangladesh si n ra bi ida ọgọrin ti wọn lati Indonesia.

Anfaani nla ni bi Indonesia ṣe fi ofin de tita epo silẹ okeere jẹ fun Africa

Connie Magomu, to jẹ oludari ajọ to n mojuto ipese epo pupa ni Uganda, sọ pe ilẹkun anfaani nla lo ṣi, bi Indonesia ṣe ṣe ofin tuntun.

Magomu sọ pe o jẹ anfaani fun awọn orilẹ-ede ni Africa, lati mu idagbasoke ba ẹka ọrọ aje epo pupa wọn.

O ni "nkan ọgbin to ma n din ìṣẹ́ kù ni epo pupa, nitori pe igi ọpẹ kan ṣoṣo ma n pese epo fun ogun ọdun si ọdun mẹẹdọgbọn".

Igbesẹ ti Indosia gbe yii ṣe e ṣe ko mu ki oju ṣi si Naijiria

Naijiria ni olupese epo pupa julọ ni Africa lọwọlọwọ, oun si ni l'agbaye ṣaaju ọdun 1970.

Bayii, o ṣe e ṣe ki owo awọn nkan elo ti wọn n fi epo pupa ṣe bii ororo, ọṣẹ, ipara, bọta ati awọn nkan jijẹ ati aṣaraloge miran, ko wọn si.

Uganda ti n mu idagbasoke ba ẹka epo pupa rẹ diẹdiẹ, ṣugbọn o ṣi nilo ẹgbẹrun lọna ọgọrun eeka ilẹ, ko to o le pọ yanturu.

Awọn orilẹ-ede Africa mii ti anfaani tuntun yii le mu idagbasoke ba ni Naijiria, Ghana, Ivory Coast, Sierra Leone, Uganda, Burundi, DRC Congo ati Tanzania.