Popular areas in Ibadan: Àwọn àdúgbò tó gbajúmọ̀ jùlọ nílùú Ibadan rèé àtàwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa wọn

Ilu ibadan ni olu ilu ipinlẹ Oyo, oun si ni ilu ti ero pọ si julọ ni ipinlẹ naa.

Ipo kẹta ni ilu ibadan wa lara awọn ilu to tobi julọ ni Naijiria lẹyin ilu Eko ati ilu Kano to wa loke ọya, iye eeyan to n gbe ni ilu Ibadan ko din ni miliọnu mẹta ati abọ.

Yatọ si ọpọ ero, oriṣiriṣi awọn adugbo ati agbegbe lo wa ni ilu Ibadan ti orukọ wọn si lamilaaka kaakiri orilẹ-ede Naijiria ati kaakiri agbaye, awọn agbegbe naa ree:

Iwo Road

Ko si ẹni ti ko mọ Iwo road niluu Ibadan, yala ẹni naa jẹ olugbe ilu Ibadan tabi awọn arinrinajo ti wọn n gba inu Ibadan kọja.

Agbegbe naa jẹ eyii to gbajumọ nitori bi o ṣe wa ni aarin ọna to n bọ lati Eko si Ogbomosho, Akure-Ilesha, ati bẹẹ lọ.

Iwo road wa ni ijọba ibilẹ Ariwa-Ilaorun Ibadan, o si sun mọ oriṣiriṣi ibudokọ.

Bẹẹ si ni ọpọ ile ifowopamọsi, ile ounjẹ, ọja, ile igbafẹ ati bẹẹbẹẹ lọ yi Iwo road ka.

Challenge:

Agbegbe miran to tun gbajumọ daadaa ni Challenge jẹ niluu Ibadan.

Orita Challenge ko jina pupọ si ọna marosẹ ilu Eko si Ibadan, to n tumọ si pe o rọrun lati tete gba agbegbe naa lọ siluu Eko.

Oriṣiriṣi ile igbafẹ ati ibi ti eeyan ti le ṣe faaji lopin ọsẹ lo wani Challenge, eeyan si le gba Challenge lọ ile itaja igbalode Ibadan Shopping Mall, ti ọpọ mọ si Shoperite.

Sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ maa n waye ni Challenge lọpọ igba nitori agbegbe to wa ati nitori bi ọpọ ọkọ ṣe maa n gba agbegbe naa kọja.

Ogunpa

Ogunpa ko laṣimọ niluu Ibadan, o si gbajumọ gidi ni aye tirẹ.

Ti ẹ ba n fẹ aṣọ olowo pọku tabi olowo iyebiye, ẹyin ẹ ṣa ti tẹkọ leti lọ si Ogunpa.

Bakan naa ni ti ẹ ba n wa awọn ọja nla ni Ibadan, yatoo si Gbagi, Ogunpa naa ni ki ẹ kori si.

Gate

Gate gbiyanju lara awọn agbegbe to lamilaaka ju niluu Ibadan.

O sun mọ ọpọ ibudokọ ati ọja, paapaa awọn ẹya ara ọkọ ati alupupu.

To n tumọ si pe ti ẹ ba n wa ẹya ara ọkọ ati alupupu atawọn nnkan mii niluu Ibadan, Gate ni ki ẹ maa lọ.

Bodija

A ko le sọrọ nipa awọn agbegbe to halẹ niluu Ibadan lai mẹnuba Bodija.

Ohun kan pataki ti Bodija gbajumọ fun ni ọja rẹ, ti wọn pe ni Ọja Bodija.

Wọn da ọja Bodija silẹ lọdun 1987 lẹyin ti awọn ero ilu Ibadan bẹrẹ si n pọ si, paapaa lasiko ti ẹsẹ ko gbero mọ ni ọja ounjẹ Orita Mẹrin.

Eyii lo mu ijọba Ologun ipinlẹ Oyo, labẹ iṣakoso Tunji Olurin lọdun naa lọhun da bi ọgbọn lati gbe ọja Bodija kalẹ ni 1987, ti wọn si dari ọpọ awọn oniṣowo ọja Orita Mẹrin naa lọ si Bodija.

Bẹrẹ

Lara awọn ilu to gbajumọ julọ niluu Ibadan naa ni Bẹrẹ wa, paapaa ọja Bẹrẹ.

Bere tun jẹ ọkan lara awọn agbegbe ti awọn ile atijọ wa ju niluu Ibadan.

Bere yii kan naa ni ọkan lara awọn ọja to tobi julọ niluu Ibadan wa.

Ko tan sibẹ, ti ẹ ba fẹ ra ogidi ọkọ́ tabi oriṣiriṣi awọn iwe fun awọn akẹkọọ, ọja bere ni ẹ ya si.

Mokola

Mokola gbajumọ fun awọn ṣọọbu ti wọn ti n ta ẹrọ ibaraẹnisọrọ niluu Ibadan atawọn ẹya ara ẹrọ ilewọ.

Awọn kan tilẹ maa n fi Mokola we Computer Village niluu Eko nitori oniruru awọn ṣọọbu ti wọn ti n foonu nibẹ, ati bi awọn kọlọrọrọsi kan ṣe maa n lu gbajuẹ lagbegbe ọhun.

Sango

Sango jẹ agbegbe kan to laju daadaa niluu Ibadan, eyii ko si ṣẹyin bi awọn akẹkọkọọ fasiti Ibadan, UI ati ile ẹkọ gbogboniṣe Ibadan Poly ṣe pọ mọ agbegbe ọhun.

Lara awọn ileeṣẹ Pataki to sun mọ Sango ni ọọfisi ileeṣẹ to n ri si idanwo aṣekagba ile ẹkọ girama ni Afrika, WAEC, ati ọgba ẹranko.

Dugbe

Ijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-oorun Ibadan ni Dugbe wa.

Agbege naa si gbajumọ fun oriṣiriṣi ile iṣẹ atawọn ile ifowopamọ niluu Ibadan.

Ọpọ lo gbagbo pe Dugbe ni aringbungbun awọn ile iṣẹ ati okoowo niluu Ibadan, bẹẹ ni wọn ko parọ.

Lara awọn ileeṣẹ to yi Dugbe ka ni Ọja Dugbe, Shoperite, ibudokọ ọkọ oju irin ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Molete

Molete jẹ ọkan Pataki lara awọn agbegbe to kọkọ gbinlẹ ni Guusu ila-oorun ilu Ibadan.

Molete kan yii naa ni ile ẹkọ akọkọ wa niluu Ibadan, iyẹn Ibadan Grammar School, ti wọn da silẹ lọdun 1913.