Olufon: Ọba Almaroof Adekunle Magbagbeola Olumoyero II, òsìṣẹ̀ àjọ NNPC tó di ọba Ifọn

Olufon ti ilu Ifon-Orolu ni ipinlẹ Osun, Ọba Almaroof Adekunle Magbagbeola Olumoyero II ti tẹri gbaṣọ.

Ori ade naa waja lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2021 ti a wa yii.

Iroyin ti a gbọ sọ pe Kabiesi mi imi ikẹyin rẹ nile iwosan kan lẹyin aisan ranpẹ.

Wọn bi Ọba Almoroof Adekunle Magbagbeola ni bi i ọdun 1950.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ Yoruba ni, to si jẹ ọmọ Naijiria, orilẹ-ede Ghana ni wọn bii si, nitori pe ibẹ ni awọn obi rẹ fi ṣe ibugbe lasiko naa.

Ọdun 1964 ni igba akọkọ to wa si orilẹ-ede Naijiria lẹyin ti iya agba rẹ sọ pe dandan ni fun un lati pada si Naijiria.

Nitori naa si lo ṣe fi Ghana silẹ, to wa si ilu Oṣogbo lati ma a gbe pẹlu iya agba naa.

Ṣugbọn lẹyin to pari ileewe alakọbẹrẹ, Magbagbeọla sa pada si Ghana, nitori pe ko gbọ, bẹẹni ko le sọ ede Yoruba daadaa.

Ede Ashanti ati Gẹẹsi lo mọ.

Itan sọ pe awọn obi rẹ ni ile to pọ ni Ghana, ṣugbọn wọn fi gbogbo rẹ tọrẹ nigba ti wọn fẹ ẹ pada si Naijiria lọdun 1967 lasiko ti awọn alaṣẹ Ghana paṣẹ pe ki gbogbo ọmọ Naijiria to wa nibẹ pada si orilẹ-ede wọn.

Idile marun-un lo maa n jẹ ọba ni ilu Ifon-Orolu, lara wọn ni Olumoyero ti Ọba Magbagbeọla ti wa.

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2007 ni wọn fi jọba ilu Ifon nipinlẹ Ọṣun.

Ṣugbọn ṣaaju asiko naa, oṣiṣẹ ajọ to n mojuto epo rọbi ni Naijiria, NNPC ni. Ipo alamojuto (supervisor) lo wa ni ẹka iṣakoso ileeṣẹ NNPC nilu Warri, nipinlẹ Delta.

Ọdun mẹẹdọọgbọn lo fi ṣiṣẹ pẹlu NNPC.

Yatọ si pe o jẹ ọba ilu Ifọn nipinlẹ Ọṣun, oun naa tun ni ọba ilu Ilobu ati Erin-Osun.

Ẹwẹ, awọn abanikẹdun, ti ọpọ ninu wọn jẹ ọmọ ilu ti kabiesi naa jọba le lori nigabaye rẹ ti n korajọ si aafin rẹ lati ṣedaro.

Adura wa ni pe ki Ọlọrun tẹ baba si afẹfẹ rere, ẹyin ti wọn fi silẹ ko si ni bajẹ.