Ooni Ile Ife: Emir Kano bẹ ààfin Ọọ̀ni wò, Ọọni Ogunwusi ṣàlàyé ìpayà tó gbòde lórí yíyọ tí Ganduje yọ Sanusi lóyé Emir Kano

Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi ni ibẹru bojo gbode nigba ti ayipada ipo waye ni ilu Kano nitori gbogbo eeyan lo mọ pe bi wahala ba ṣẹlẹ ni ilu Kano, nnkan o lee rọrun lorilẹede Naijiria.

Ọọni ile ifẹ ṣalaye pe nigba ti ijọba ipinlẹ Kano rọ Emir Sanusi Lamido Sanusi loye to yan Emir Ado Bayero sipo, ọkan ọpọ eeyan lo n gbọn riri nitori ko si ẹni to mọ ibi ti afẹfẹ ọrọ naa yoo fẹ si.

Ọọni Adeyẹye Ogunwusi sọrọ yii lasiko ti Emir ilu Kano, Alhaji Ado Bayero bẹ ẹ wo ni aafin rẹ nilu Ile Ifẹ.

"Ọlọrun ṣeun fun alaafia to jọba nigba ti Emir tuntun joye ni ilu Kano. Gbogbo wa lẹru ba lori iyipo pada to waye ni Kano nitori a mọ pe wahala yoo wa ni Naijiria bi wahala ba bẹ silẹ ni ilu Kano, ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe alaafia jọba."

Ọọni Ogunwusi ṣalaye pe lara ohun to mu alaafia jọba lorilẹede Naijiria ni irẹpọ to wa laarin awọn ọbalaye, paapaa julọ gẹgẹ bi Ọọni ana, Okunade Sijuwade Olubuse II, Emir ana ni ilu Sokoto, Alhaji Ado Bayero pẹlu Obi ana ni ilu Onitsha ṣe ba ara wọn dọrẹ pọ, eleyi to ni o ṣe ọpọlọpọ anfani fun orilẹede Naijiria.

Bakan naa ni Ọọni Ogunwusi tun ke sawọn agbaagba lorilẹede Naijiria lati ṣilẹkun silẹ fawọn ọdọ nitori, gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn lo ni orilẹede Naijiria.

"Ẹ jẹ ki a kọ wọn, ki a tun tun wọn kọ, eyi gan ni yoo mu idẹrun ba wa. A ko ni lati duro de ijọba, ki olukuluku ṣe ipa tirẹ lo tọ."

Ṣaaju ninu ọrọ rẹ ni Emir ilu Kano, ti pe fun, 'ajọṣepọ ati ajumọkẹgbẹ pọ lati finuwenu lori gbigbogun ti iṣoro to n koju eto ẹkọ, igbanisiṣẹ ati idagbasoke ilu laarin awọn ọdọ lorilẹede Naijiria nitori nipasẹ eyi ni ọna abays fun iṣoro atigbadegba to n koju orilẹede Naijiria lee ti yọju.'