You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ooni Ile Ife: Màmá tó bí ìyá Ọọ̀ni ilé Ifẹ̀ ju awà sílẹ̀ lẹ́ni ọdún 103
Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji ti padanu Iya-iya rẹ, iyaafin Comfort Faramọbi Ajọkẹ Ọlasọji Sọji-Ọpa.
Agbẹnusọ fun Aafin ile Oodua, Moses Ọlafare to fidi eyi mulẹ ni aṣalẹ ọjọ Aiku ṣalaye pe ẹni ọdun mẹtalelọgọrun ni iya naa ki ọlọjọ to de.
- 'Ìbọn dún láàfin Ọ̀ọ̀ni ilé ifẹ̀ lóòtọ́, ṣùgbọ́n kò séwù'
- Aláàfin Ọyọ: Ọba tó bá n mú ọtí ní ìta kò yẹ ní ẹni tàá bọ̀wọ̀ fún
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
- Ilẹ̀ ifẹ̀ ní ìran Ìgbò tí ṣẹ wá kìí ṣe ilẹ̀ Juu - Ọọni
- N kò ni nkan kan sọ lórí fídíò to gba ayélujára kan pé mo ń we igbó, ẹ mú ẹnu kúrò nibẹ - Oluwo
Iya-iya Ọọni Ogunwusi, ti ọpọ mọ si 'Mama Agba'nigba aye rẹ ni wọn ṣalaye pe o jẹ gbajums oniṣowo ti wọn bi ni ọdun 1907 si idile Oloye Aina Akinyẹmi ni agboole Ajigbayin ni ilu Ile Ifẹ.
Awọn ohun jijẹ ni ilu mọ iya naa fun nigba ṣango ode rẹ ti ko si si ẹni ti ko fẹrẹ maa mọọ ni ọja Itaakọgun, Ọja titun atawọn ọja miran ni ilu Ile Ifẹ ati agbegbe rẹ.