You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ada Jesus dead: Wo àwọn nǹkan tí o lè má mọ̀ nípa Ada Jesus tó jáde l'áyé
Awaye maa ku kan ko si, ọrun nikan lare mọ bọ. Ṣugbọn adura ti onikaluku maa n gba naa ni pe ki a maa ku ni lewe.
Ọpọ lo ti n ṣe idarọ adẹrin poṣonu, Ada Jesus to jade laye lọmọ ọdun mẹtalelogun.
Wo awọn ohun ti o yẹ ki o mọ nipa apanilẹrin Ada Jesus to jade laye.
- Bobrisky sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tí kò fi kópa nínú àwẹ̀ Ramadan tó ń lọ lọ́wọ́
- Sanwo-Olu àti Osinbajo ẹ gbà mí o, mo ti jẹ gbèsè - Iyabo Ojo figbe ta
- Sotayo Gaga bẹ́ "speaker" ọdún tó ti ṣegbéyàwó àti ohuin tó fi pamọ́
- Apanilẹ́rìn, Ada Jesus ti jáde l'áyé
- Mo ti fi iṣẹ́ akọ̀ròyìn sílẹ̀, iṣẹ́ ajíhìnrere Jesu ni ọpọ́n sún kàn- Kemi Olunloyo
- Wo fọ́tò àrà MC Oluomo, Pasuma àtàwọn òṣèré tíátà míì níbi ìṣílé Iyabo Ojo
Apanilẹrin, Ada Jesus sọ fawọn eeyan nipa ailera ara rẹ nigba to wa loke eepẹ.
Mercy Mmesoma Obi ni orukọ adẹrin poṣonu to ṣalaisi, inagijẹ lasan an ni Ada Jesus.
Ọjọ meji ṣi ọjọ ti o dagbere faye ni Ada Jesus ṣe ọjọ ibi rẹ.
Lọdun 2017 ni Ada Jesus bẹrẹ si ni ṣe fidio to fi n pa awọn eeyan lẹrin lori ẹrọ Instagram.
Ko si ẹni to le sọ pato igba to bẹrẹ iṣẹ apanilẹrin gan an, ṣugbọn o ti ṣere nibi oriṣiiriṣii ayẹyẹ.
Ṣugbọn Ada Jesus di ilumọọka nitori bi awọn fidio rẹ ṣe n pa awọn eeyan lẹrin.
Ọpọ awọn fido rẹ lo ṣe ni ede Igbo lori awọn to n ṣẹlẹ lawujọ.
Ada Jesus ti ṣere pẹlu awọn ilumọọka apanilẹrin bii Sir one, Kinemaster ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lẹyin pe awọn eeyan mọ Ada Jesus si adẹrinpoṣonu, o tun maa n kọrin.
Koda, o ṣe awo orin jade pẹlu gbajugbaja apanilẹrin, Emma Mbe loṣu kọkanla ọdun 2020 ti wọn pe akọle rẹ ni ''Ada & Emma Mbe in Love.''
Ada Jesus ni awọn ololufẹ to le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn lori ero Instagram.
Apanilẹ́rìn, Ada Jesus ti jáde l'áyé
Gbajaugbaja apanilẹrin ni Naijiria, Ada Jesus ti jade laye.
Harrison Gwamnishu to ṣagbatẹru bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe dide iranlọwọ fun Ada, ti wọn si gbe lọ sileewosan fun ailera rẹ, fidirẹmulẹ fun BBC Pidgin pe o ti pada kú.
Ṣaaju ni apanilẹrin naa, ti orukọ rẹ gan-an-gan n jẹ Mmesoma Mercy Obi, sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu BBC Igbo pe oun ni aisan ninu kindinrin oun.
O sọ pe o ti fẹ ẹ to ọdun kan ti oun ti wa ni idubulẹ aisan naa.
Harrison ni "lati oṣu Kejila ni ara mi ti n wú, paapaa ikùn ati oju mi. Mi o le rin nitori pe ko si okun fun mi lati dide duro.
"Nigba ti mo lọ si ileewosan, wọn sọ fun mi pe aisan kindinrin ni mo ni, ṣugbọn ma a ri iwosan ti mo ba ni owo."
- Ìjà ẹgbẹ́ òṣèré TAMPAN àti ANTP ni kò jẹ́ kí wọ́n pe Baba Legba sínú eré mọ́, kó tó kú - Owolabi Ajasa
- Àwọn ọlọ́pàá ti dóòlà ọmọbìnrin tí àwọn òbí rẹ̀ so mọ́lẹ̀ fún ọdún 10
- Ọgbẹ́ inú mú òṣèré lọ
- Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sadiq Daba 'Inspector Waziri' nínú sinimá October 1 tó jáde láyé rèé
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa bí ọmọ ẹgbẹ́ IPOB ṣe lè jàǹfàní ṣíṣe àtìpó ní Britain
O ṣalaye pe o yẹ ki wọn o gbe oun lọ si India lati paarọ kindinrin naa.
O ni ọpọlọpọ eeyan lo ti da owo fun oun lasiko naa, amọ o ku diẹ ki owo naa pe iye to nilo fun irinajo naa.
Ọjọ Aje, ogunjọ oṣu Kẹrin ni fidio jade sori ayelujara, nipa awọn eeyan kan to ko ara wọn jọ nileewosan ti Ada Jesus ti n gba itọju, lati ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
Awọn iroyin kan ti ẹ sọ ṣaaju ọjọ naa pe ara rẹ ti n ya diẹdiẹ.
Nigba ti iroyin ailera rẹ jade ni ibẹrẹ ọdun yii, ọpọ eeyan lo sọ pe gbajugbaja wooli, Chukwuemeka Odumeje, babalawo kan, Chi Marine Temple, ati oṣerebinrin, Rita Edochie lo wa nidi aisan to n sẹ.
Iroyin sọ pe Ada Jesus sọ awọn ọrọ iwọsi ati abuku si awọn eeyan naa ninu awada rẹ.
Awọn mẹtẹẹta si ti sọ pe awọn ti dari ji i.
Koda, Chi Marine ati Odumeje fi owo ranṣẹ si ẹbi rẹ lati fi tsju rẹ, ṣugbọn awọn ẹbi naa sọ pe awọn ko nilo rẹ.
- "Iṣẹ́ fọga ni mo fi kọ́ ilé ńlá méjì, ti mo sì fi rán àwọn ọmọ mi lọ fásitì"
- Kí ni ìdí tí àwọn ọmọ Naijiria ṣe fẹ́ kí Isa Pantami kọ̀wé fi ipò sílẹ̀?
- Ṣé lóòtọ́ ni Sotayo Gaga ti di ìyá Ọba nílẹ̀ Hausa?
- Wo àtúpalẹ̀ nkan tí òmìnira tí àwọn gómìnà fi ọwọ́ sí fún ẹ̀ka ìdájọ́ Naijiria túmọ̀ sí
- Ọwọ́ NDLEA tẹ akẹ́kọ̀ọ́ fásitì tó n ta 'cookies' tí wọ́n fi oògùn olóro ṣe fún àwọn ọmọ́de