Bobrisky 2021 Ramadan: Wo ìdí tí Bobrisky kò fi kópa nínú àwẹ̀ Ramadan tó ń lọ lọ́wọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ko ṣeku ko ṣẹyẹ nipa aṣọ obinrin ati ọkunrin wiwọ, Okuneye Idris Olanrewaju ti ọpọ mọ si Bobrisky ti ṣalaye idi ti ko fi kopa ninu awẹ Ramadan to n lọ lọwọ.

Bobrisky sọ loju opo Instagram rẹ pe nkan oṣu oun ni ko foun laye lati gba awẹ awọn musulumi to n lọ lọwọ.

''Awọn eeyan ti n bi mi leere bo ya mo n gba awẹ, ṣugbọn mo n dawọn lohun pe mo n ṣe nkan oṣu mi lọwọ.

Gẹgẹ bi ẹsẹ mọ, awẹ awọn obinrin kii pe,'' Bobrisky lo sọ bẹẹ lori ẹrọ Instagram.

Ẹwẹ, ero awọn eeyan ṣe ọtọtọtọ lori gudugbẹ ọrọ ti Bobrisky ja lulẹ loju opo Instagram rẹ.

Iyalẹnu lọrọ yii jẹ fawọn ololufẹ Bobrisky kan ti wọn ka ọrọ to fi lede loju opo Instagram rẹ.

Oloribecca ni tẹ sọ pe ọrọ ti Bobrisky sọ fẹ mu oun daku rangbọndan nigba ti awọn kan bu si ẹrin gbagada.

Ogebaby ni tiẹ beere lọwọ Bobrisky pe ṣe nkan oṣu rẹ ko mu inira wa fun un.

Annabelle bu si ẹrin gbagada ni tiẹ, o ni Bobrisky ko ni fi ẹrin pa oun niluu Eko.