#born again christian: Mo ti fi iṣẹ́ akọ̀ròyìn sílẹ̀, iṣẹ́ ajíhìnrere Jesu ni ọpọ́n sún kàn- Kemi Olunloyo

Mo ti fi iṣẹ akọroyin silẹ o, iṣẹ ajihinrere Jesu lo kan - Kemi Olunloyo

Akọroyin lori ẹrọ ayelujara, Kemi Olunloyo ti kede wi pe oun ti fi iṣẹ akọroyin silẹ lati bẹrẹ iṣẹ ajihinrere 'evangelist' ni pẹrẹwu.

Kemi Olunloyo fi iroyin naa lede loju opo ikansiraẹni Instagram rẹ pe esu ti jẹbi ni aye oun, nitori oun ti di ẹni ọtun.

Akọroyin naa ni ọdun 2017 ni oun gba Jesu Kristi ni Oluwa ati olugbala oun.

''Ọdun 2019 ni mo bẹrẹ iṣẹ ajihinrere, ti ọpọ eniyan ko si kọbi ara si iṣẹ ihinrere mi, amọ mo ti oju opo ihinrere mi ni asiko Ajinde ni ọdun 2020.''

''Idi ti mo fi fẹ fi iṣẹ akọroyin silẹ ni wi pe ko si ̣ẹ̣ni to gba iroyin mi gbọ lasiko iṣẹ mi gẹgẹ bi akọroyin, awọn eniyan ko bikita nipa nkan ti mo ba kọ.''

Amọ, lẹyin ọdun 2020 naa, gbogbo ọrọ ati iwadii ti Kemi Olunloyo ti ṣe gẹgẹ bi akọroyin bẹrẹ si ni wa si imuṣẹ.

''Mi o fi ti awon elegan se, mob ere si ni tesiwaju ninu ise mi.

Kemi Olunloyo ni: ''Amọ mo fẹ pada si orilẹede Amerika bayii lati lo kawe si ninu eto ẹkọ imọ ipoogun ti mọ ti n se bọ ni ọjo ̣to ti pe.

Bakan naa ni Kemi Olunloyo ni oun ti bẹrẹ si ni ka itan igbesi aye oun, eleyii ti yoo jade ni aipẹ.

Ni ti iṣẹ ajihinrere, Olunloyo ni Oluwa ran oun si ạwọn ọdọ paapaa ti wọn ba n wa ọrọ Olorun.

O rọ awọn eniyan lati tẹlẹ oju opo ikansiraẹni Instagram oun lati mọ bi o ṣe n lo ninu irinajo gẹgẹ bi ajininrere rere, amọ ko si iṣẹ akoroyin mo.