OAU Ile Ife: Àwọn nǹkan tó ka akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU Ile Ife, Emmanuel Adedeji láya ló mú kó gbẹ̀mí ara rẹ̀

Iroyin jade lọjọ Iṣẹgun pe akẹkọọ onipele keji ẹka eto ẹkọ nipa iṣakoso ati iṣiro owo ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, OAU ni ilu Ile Ifẹ ni ipinlẹ Ọṣun ti gba ẹmi ara rẹ.

Akẹkọọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Emmanuel Adedeji gba ẹmi ara rẹ lẹyin ti wọn ni o gbe oku apakokoro jẹ.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, alukoro ileewe fasiti OAU, Ọgbẹni Abiọdun Ọlarewaju ṣalaye pe lootọ ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ati pe o ṣeeṣe ki o jẹ pe nnkan kan lo ka ọmọdekunrin naa laya to fi igbesẹ naa.

Alukoro naa fi kun un pe lootọ awọn alaṣẹ ileewe naa ko lee sọ boya ẹkọ rẹ ni, nitori pe ko si akọsilẹ kankan to fihan pe o ni iṣoro lẹnu ẹkọ rẹ tabi maaki to n gba'

Koda, o ni o lee jẹ ohun to n lọ layika rẹ to yatọ si eto ẹkọ.

Gẹgẹ bi Alukoro naa ṣe tun ṣalaye siwaju pe awọn alaṣẹ ileewe naa ti ranṣẹ si awọn obi rẹ ti wọn si ti bawọn kẹdun lori iku ọmọ wọn.

O ni akẹkọọ naa ni abigbẹyin awọn obi rẹ, baba rẹ ti ku, bẹlni iya ati ẹgbọn rẹ ni wọn n tọọ.

Alukoro fasiti OAU naa wa rọ araalu lati maa gba awọn ọdọ to ba wa layika wọn lamọran lori ifarada ati ibi gbogbo to wa ninu ire laye ati layika wọn.