You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Adebimpe Oyebade and Lateef Adedimeji: Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, wọn kò ṣe é gbáralé
Ggbajugbaja oṣere Nollywood, Adebimpe Oyebade, ti kegbare sita pe ẹlẹtan ni awọn ọkunrin.
Nibu ọrọ kan to kọ soju opo ayelujara Instagram rẹ lo ti n beere lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe, ki lo maa n mu ki awọn ọkunrin yi iwa wọn pada si obinrin ti wọn n fẹ, lẹyin ti ibalopọ ba ti waye laarin awọn mejeeji.
O ṣalaye pe kii ṣe obinrin nikan lo ma n ṣe oju meji tabi jẹ ọdalẹ ninu irinajo ifẹ, o ni ati ọkunrin ati obinrin lo ni iwa yii lọwọ.
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Adedimeji?
- Ọdún mọ́kànlá rèé témi àti ọkọ mi bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́ láti ilé ẹ̀kọ́ girama - Bukunmi Oluwasina
- Saheed àti Fathia Balogun dìjọ ń ṣe ọjọ́ ìbí lónìí, ẹ wo àjọṣepọ̀ tó wà láàrin wọn
- Ìrìnàjò Toyin Abraham, láti orí gbèsè jíjẹ, ó di onílé, onimọto àti aya lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ
O tọka si bi oriṣiriṣi ọkunrin ṣe ma n yi iwa pada si obinrin, ti obinrin naa ko si ni ri oju wọn nilẹ mọ, lẹyin ti ọwọ ọkunrin bẹẹ ba ti tẹ nkan to n wa ninu irinajo ifẹ naa.
Ọrọ naa waye lori fidio kan to fi sita, ninu eyi ti oun ati akẹẹgbẹ rẹ, Adedimeji Lateef, ti ṣe ere kekere kan, ninu eyi ti awọn mejeeji ti jẹ ololufẹ.
Ninu fidio naa, to jẹ apa kẹrin eto kan ti Adebimpe ma n ṣe, lo pe akori rẹ ni 'DiaryOfAnAfricanWoman EP 4 - MEN ARE SCUM'.
Ninu fidio naa, awọn mejeeji fẹran ara wọn pupọ, ṣugbọn lẹyin asiko diẹ, Lateef ko gbe ipe Adebimpe mọ lori foonu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- A kò le gbà kí ASUU gba ₦30bn nínú ₦40bn tíjọba gbé kalẹ̀ - NASU yarí
- Ẹ̀yin adarí Nàíjíríà, ẹ dẹ́kun àwáwí asán lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ - Ààrẹ àṣòfin àgbà
- Ẹ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, ohun tó pa ẹ̀gbọ́n àti àbúrò Orisabunmi rèé - Mọ̀lẹ́bí gbarata
- Wo àdánù tó wà nínú gbígba ayédèrú áápù fún ìforúkọsílẹ̀ NIN lórí ayélujára
- Àmúlò ẹ̀rọ POS fun òwò ṣíṣe, ṣé ó tọ̀nà nínú Islam àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
- Ìjọba ń ṣapá rẹ̀ lórí ìdènà Covid-19 àmọ́ àwọn awakọ̀ Eko ya aláìgbọràn - Ìjọba
- "Ẹ̀yin tẹ̀ ń parọ́ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà mọ́ Amotekun Oyo, Seyi Makinde lẹ̀ ń dojú ìjà kọ"
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
Ibalopọ to ti waye laarin wọn di oyun, amọ niṣe ni Lateef kọ lati gba oyun, to si sọ fun Adebimpe pe, awọn obi oun ko faramọ ki awọn fẹra gẹgẹ bi ọkọ ati iyawo.
Adebimpe beere pe ,ki lo de ti awọn ọkunrin kan ma n tan obinrin, nigba ti wọn mọ pe awọn ko ni erongba lati fẹ ẹ sile?
O ni ti ọkunrin ba ṣẹṣẹ n fẹ obinrin, o ma n fi aaye silẹ lati wa pẹlu rẹ, ṣugbọn to ba ti kọja lara rẹ tan, aye lati rira ko ni i si mọ.
O wa sọ fun awọn ọkunrin pe, ki wọn yi iwa pada, ki wọn o ṣe obinrin bi wọn ba ṣe fẹ ki ọkunrin mii ṣe si ọmọ wọn obinrin.