Saheed-Fathia Balogun: Ọjọ́ Karùn-ún oṣù kejì ni wọ̀n bí wọn, tí wọn sì bí ọmọ méjì fúnra wọn

Ọjọ ibi se pataki, o se koko, bẹẹ si ni inu ẹni kii dun ka pa mọra ni ọjọ ibi ẹni.

Bẹẹ ni ọrọ ri lọjọru, ọjọkarun osu keji ọdun 2020 nigba ti tọkọ-taya tẹlẹ, Saheed Balogun ati aya rẹ tẹlẹ, Fathia Balogun dijọ se ọjọ ibi wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kii wọpọ ki tọkọtaya dijọ maa se ọjọ ibi wọn ni ọjọ kanna, idi si ree ti ọrọ ajọsepọ Saheed ati Fathia fi yatọ pupọ, bi o tilẹ jẹ pe wọn ko jọ gbe papọ mọ.

Ajọsepọ wo lo wa laarin Saheed ati Fathia Balogun:

  • Ọjọ karun osu keji ni wọn bi Saheed ati Fathia, bi o tilẹ jẹ pe ọdun 1967 ni wọn bi Saheed nigba ti wọn bi Fathia lọdun 1969
  • Eyi tumọ si pe ọjọ to pe ọdun meji geerege ti wọn bi Saheed, ni Fathia naa dele aye
  • Ilu Enugu ni wọn bi Saheed si nigba ti wọn bi Fathia si Ikeja, nilu Eko
  • Ọmọbibi ilu Ibadan nipinlẹ Ọyọ, ni agboole Balogun Kọbọmọjẹ ni Saheed nigba ti Fathia jẹ ọmọ ilu Ukwara, nipinlẹ Delta
  • Saheed ka iwe alakọbẹrẹ ati girama rẹ ni ipinlẹ Ọyọ, ko to morile ile ẹkọ gbogbo nse Poly tipinlẹ Kwara lati tẹsiwaju
  • Fathia kawe alakọbẹrẹ ati girama nilu Eko, koun naa to morile ileẹkọ gbogbo nse Poly tipinlẹ Kwara yii kannaa lati tẹsiwaju ninu ẹkọ rẹ
  • Iwe ẹri Diploma ni awọn mejeeji dijọ gba jade nile ẹkọ naa, ti wsn si dijọ gba idi ere tiata lọ
  • Ilumọọka osere tiata, adari sinima ati olootu ere tiata ni Saheed ati Fathia Balogun, ti wọn si dijọ kopa to giriki ninu ere tiata lorisirisi
  • Lara awọn ere tiata to gbajumọ ti Saheed ti kopa ni Mo dupẹ temi, Gbogbo ere, Eti Kẹta, Ofin Mose ati bẹẹ bẹẹ lọ
  • Lara awọn ere to gbajugbaja julọ ti Fathia ntiẹ ti kopa ni Iransẹ Aje, Iya Alalakẹ, Farayọla, Ajẹ mẹta, Awawu, Tẹni tika, Ọmọ Ale, Basira Badia, Sola Arikusa ati bẹẹ bẹẹ lọ
  • Saheed ati Fathia gba ami ẹyẹ ti ko lonka ninu isẹ ti wọn yan laayo yii lorilẹede Naijiria ati loke okun
  • Saheed ati Fathia di tọkọtaya, ti wọn si bi ọmọ meji fun ara wọn, orukọ awọn ọmọ naa ni Khalid, ti wọn bi lọdun 2002 ati Aliyah Balogun, ti wsn bi lọdun 2005
  • Ọdun 2006 ni Saheed ati Fathia pinya bii tọkọ taya, amọ ofin sẹsẹ pin wọn ka lọdun 2014 ni bi o tilẹ jẹ pe awọn mejeeji si n sisẹ papọ

A wa n ki Saheed ati Fathia Balogun ku oriire ọjọ ibi wọn.

Lateef Adedimeji rèé tó mú omi lójú àwon òbí rẹ̀ lọ́jọ́ ẹ̀yẹ

Opin ọsẹ to kọja yii ni gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Adedimeji Lateef ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kẹrinlelọgbọn rẹ loke eepẹ.

Nibi ayẹye naa to waye ladugbo Ikeja, lo ti ṣe ere ori itage ti oun nikan da ṣe, to si danikan ko ipa eeyan mejila ninu ere naa.

Akọle ere ọhun ni Ọmọ Prime Minister.

Ọpọ awọn akẹẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata bii Iyabo Ojo, Femi Adebayo, Bimbo Thomas, Bimbo Oshin ati bẹẹ bẹẹ lọ, lo peju sibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọhun, koda, Ọọni Ile Ife wa nibẹ pẹlu.

Ayẹyẹ ọhun dun, gbọngbọn kan si, eyi lo mu omije bọ loju awọn obi rẹ nigba ti wọn pari ajọyọ ọhun.

Nigba ti Lateef n ṣafihan aworan igba ti awọn obi rẹ domije ayọ loju lori opo Instagram rẹ, o ni "Iya mi, iya Lati, omije ayọ ni."

O tẹ siwaju pe "Iya mi, iya Oluwasegunfunmi, mo ni ifẹ rẹ mama mi."

Lateeef tun kan sara si baba rẹ loju opo Instagram ọhun kan naa, nigba to ni "Baba mi, baba ti ko gba gbẹrẹ, mo ni ifẹ rẹ gan ni baba mi."

Bẹẹ naa lo tun kan sara si awọn ibatan rẹ fun aduroti wọn.