ISWAP vs Muric: À kò ni ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwón agbésùmọ̀mí- Ishaq Akintola

Ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ àwọn Sahara Strategy Group (SSG) ti rọ ìjọba àpapọ láti wádìí àbájáde ẹgbẹ́ Muslim Rights Concern (MURIC)

Wọ́n ní eyí ṣe pàtàkì nítori wọ́n gbá ẹgbẹrun lọ́nà igba dọ́lá lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí Islamic State For West Africa Province (ISWAP).

San Louis Keita to jẹ olórí ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní Mali ló fẹ̀sùn náà kàn lọ́jọ́ Jimọ, ọjọ́ keje, oṣù kẹ̀jọ, ọdún 2020 níbi ìpàdé àwọn oníròyìn kan tó pè ni Abidjan tí i ṣe olúùlú Ivory Coast.

San Louis ní wọ́n gba owó náà láti gba àwọn ọmọ Fulani kéékèké ti wọ́n n gbé ìhà Ìwọ̀ òòrùn-gúúsù Nàìjíríà.

Ẹ̀wẹ̀, MURIC ti ké gbàjàré pé òun kò mọ ǹkan kan nípa rẹ̀.

Àwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ musulumi náà sàpèjúwe ẹ̀sùn náà bi ìwà ìkà àti irọ́ pọ́nbélé láti inú ọ̀gbùn àìlópin.

Èsì MURIC yìí wà nínú àtẹ̀jáde to adári ẹgbẹ́ náà ọjọ̀gbọ́n Ishiaq Akintola fọwọ́ sí lọ́nìí ọjọ́ Isẹgun, ọjọ kọkànlá, osú kẹjọ, 2020.

Àtẹjàdè náà kà báyìí pé:

A ṣe àkíyèsí pé àwọn kan ń ṣe àhesọ ọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀rọ àkànsiraẹni káàkiri pe MURIC gbá ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba dọ́là lọ́wọ́ ISWAP.

Ìwà ìkà àti ìbanilórúkọ jẹ́ ni, mo sì sọ gbangba-gbàǹgbà pé, a kò tii fi ìgbà kan ké si ISWAP tàbi ẹgbk agbésùmọ̀mí kankan fún ohunkóhun.

Katsina: Àwọn agbébọn gbẹ̀mí àgbẹ̀ márùndínlógún ní Katsina

Ileeṣẹ ọlọpaa ariwa-iwọ oorun Naijiria ti sọ pe awọn agbebọn ti pa awọn agbẹ marundinlogun labule kan ni ipinlẹ Katsina.

Wọn ni ṣe ni awọn agbebọn naa ti iye wọn to igba bẹrẹ si ni yinbọn awon lu eeyan to n ṣiṣẹ ni oko kan to wa ni abule Yargamiji.

Ko din ni ọgọrun eeyan to ti dero ọrun nipasẹ iru akọlu bẹ ni ipinlẹ ọhun laarin oṣu Kẹrin si oṣu Kẹfa ọdun yii.

Agbẹnusọ ọlọpaa, Gambo Isah sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe alupupu ni awọn agbebọ ọhun gun lọ ṣe iṣẹ ibi naa.

Iroyin ni ọjọ ti pẹ ti awọn agbebọn ọhun to ṣeṣe ko jẹ darandaran n kọju ija si awọn agbẹ nitori ilẹ ati omi lagbegbe naa.

O ti to nnkan bi ọdun diẹ sẹyin ti ijọba Naijiria ti ni oun yoo wa ojutu si ija laarin awọn darandaran atawọn agbẹ, ṣugbọn kaka k'ewe agbọn ọrọ naa dẹ, lile lo tun n le si.

Domestic Violence: Obìnrin tó gún ọkọ rẹ̀ pa lórí ọ̀rọ̀ fóònù ní òun si ní ìfẹ́ ọkọ òun

Obinrin kan, Rabi Rabi'u to gun ọkọ rẹ pa ti ṣalaye pe, ede aiyede to ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji lori ta ni yoo kọkọ ti fooni bọ ina lo fa sababi iṣẹlẹ naa.

Rabi, to jẹ iyawo ile sọrọ yii nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ṣe afihan rẹ lọjọ Iṣẹgun, pẹlu afikun pe oun ko mọ pe ọkọ oun le gba idi aawọ naa dero ọrun.

O ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti ileeṣẹ ina mọnamọna ṣẹṣẹ mu ina de lagbegbe tawọn n gbe, ti esu si lo oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Rabi sọ di mimọ pe, ọkọ oun, Shamsu Salisu, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn naa fẹ ti foonu tiẹ naa sina nigba kan naa pẹlu oun, eyi to fa aawọ laarin awọn mejeeji.

Amọ obinrin naa ṣalaye pe, Salisu gan lo kọkọ yọ ọbẹ jade, ki oun to gba ọbẹ naa lọwọ rẹ ṣugbọn oun ko mọ pe igbesẹ ọhun ko ni bimọ ire.

''Igbeyawo wa ko tii ju ọjọ mọkanlelaadọta lọ, a ṣẹṣẹ n gbero lati bimọ ni, bẹẹ si ni mo nifẹ ọkọ mi,'' Rabi lo woye bẹẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, Gambo Isah ṣalaye pe, ni bii aago marun un aabọ idaji lawọn gba ipe wi pe, aawọ ti bẹ laarin Salis ati iyawo rẹ labule Almakiyayi.

Isah ni iyawo Salisu gun un lọbẹ kaakiri ara rẹ to fi mọ inu, nigba ti Salisu n sun lọwọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni, wọn gbe Salisu digbadigba lọ si ile iwosan nibi to ku si nitori ẹpa ko boro mọ.

Isah ni ileeṣẹ ọlọpaa ri ọbẹ ati aṣọ bẹẹdi ti ẹjẹ wa lara rẹ ninu iṣẹ iwadii wọn.