You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Security Walk: Femi Emmanuel ni ìrìn fún ààbò dára àmọ́ kò le è tu irun kan lára ìjọba
Adari ẹgbẹ to n ja fẹtọ awọn Musulumi, MURIC, ọjọgbọn Ishaq Akintola ti sọ pe ẹgbẹ naa ko faramọ iwọde ti awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe lodi si ọrọ eto abo to mẹhẹ lorilẹede yii.
Ishaq sọ fun BBC Yoruba pe, ko tọ fun olori ẹsin lati maa gbe patako lọwọ laarin igbooro, pe oun n ṣe ifẹhonuhan lodi si ijọba.
Ọjọgbọn naa ni iwọde ọhun da bi ẹni pe awọn to kopa ninu rẹ n ba ijọba ja ni, ati pe wọn ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ni.
- Mímu ọtí líle àti oúnjẹ oní sítáṣì le è fa àrùn jẹjẹrẹ ọyàn - Onímọ̀
- Àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní Kwara sọ ara wọn sínú ààwẹ̀ àti àdúrà torí owó oṣù tuntun
- Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ PDP tó sápamọ́ kọlù mí lásìkò tí mò ń lọ sí ibi iṣẹ́, ló fa rògbòdìyàn - Olamiju Akala
- Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fáwọn obìnrin, ife ìtọ̀ tó ń dènà àrùn nílé ìgbọ̀nsẹ̀ ti dé
O ṣalaye pe, kaka ki awọn olori ẹsin maa gbe iwe ifẹhonuhan kiri, n ṣe lo yẹ ki wọn wo aarin ara wọn ki wọn si ṣe itaniji nitori awọn to n lọ ile ijọsin naa ni ọdaran.
Ishaq sọ si siwaju sii pe, awọn eeyan to kopa ninu iwọde naa jẹ alatako ijọba nitori wọn kii ri ohun rere ti ijọba n ṣe, ayafi eyii to ku diẹ kaato.
O ni iwọde naa ko lee bi ọmọ rere nitori n ṣe lo kọ awọn eeyan lati didie tako ijọba, ati pe ko kọ ijọba ni nnkan.
- Ìtàn ìgbé ayé Arap Moi, ààrẹ kejì ní Kenya tí ọ̀pọ̀ ń rántí ìjọba rẹ̀ fún ìwà àjẹbánu
- Máṣe tijú láti gé ọmú rẹ to bá ṣàkíyèsí kóró nínú ọyàn, ilèra ló ṣe kókó - Ẹni tó ye àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn
- Ìjọba Kenya kéde ọjọ́ ọ̀fọ̀ tí kò l'ópin lẹ́yìn ikú Moi
- 'Ẹ bá wa sọ fún Sanwoolu kó dárí jì wá o, ìpinú tí wọ́n ṣe l'Eko kò m'ọ́gbọ́n wá rárá'
Ni tirẹ, Pasitọ Femi Emmanuel, lati ijọ Living Spring International sọ fun BBC pe, igbeṣẹ awọn Kristẹni lati ṣe iwode jẹ igbesẹ to dara.
Bo tilẹ jẹ pe o ni iwọde naa ko le sọ ijọba to wa lode yii ji, o ni akitiyan awọn kristẹni ku diẹ kaato lori ọrọ oṣelu lorilẹ-ede yii.
O ni ko yẹ ki awọn ọmọlẹyin Kristi ati awon olori ijọ bii baba Adeboye fọwọ lẹran lori ohun to n lọ ni Naijiria.
Pasitọ ọhun ni iṣoro kan gboogi to n ba Naijira finra ni iṣoro olori, nitori naa, awọn kristẹni ni lati darapọ mọ oṣelu lọna ati yan olori rere fun orilẹ-ee yii.
O ṣalaye siwaju sii pe adura nikan ko to, ṣugbọn ijọ ni lati ji giri si ojuṣe wọn nipa kikopa ninu eto oṣelu.
Ọjọ Keji Osu Keji ọdun 2020 ni awọn Kritẹni kan ṣewọde lodi si bi nnkan ṣe n lọ ni ẹka eto aabo ati bi awọn ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram ṣe n pa awọn Kristẹni lorilẹ-ede yii, eyii ti alufa agba ijọ Irapada, E.A. Adeboye dari rẹ.