Oyo LG Crisis: Olamiju Akala ní àwọn èèyàn òun sì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ nílé ìwòsàn lórí wàhálà náà

"Irọ ni pe awọn alatilẹyin mi lo kọkọ kọlu awọn ọmọ ẹgbẹ PDP nilu Ogbomọṣọ l'ọjọ Aje."

Eyi ni ọrọ ti ọkan lara awọn alaga kansu, to tun jẹ ọmọ gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Alao Akala, eyiun Olamiju Akala, ti gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde le kuro lori oye, sọ̀,

Olamiju sọ fun BBC Yoruba pe, awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lo kọkọ kọlu awọn.

O sọ pe "Awọn ni wọn sapamọ sibikan ti wọn si kọlu wa, lasiko ti mo n lọ si ibi iṣẹ gẹgẹ bi alaga nitori pe ile ẹjọ dajọ pe emi ni.

Oju ọna la wa nigba ti wọn kọlu wa. Koda bi mo ṣe n sọrọ lọwọlọwọ, awọn eniyan wa wa ni ileewosan."

O tẹsiwaju pe iṣẹlẹ naa jẹ kayeefi fun oun, to si jẹ eyi to yanilẹnu pe, iru nkan bẹẹ le waye ni ipinlẹ Oyo.

Ni ti ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti gomina yan lati rọpo Akala, Ibrahim Ajagbe, o ni ki akọroyin wa o pe oun pada nitori pe "oun wa ni ipade".

Ni kete ti a ba ri Ajagbe ba sọrọ, ni a o mu ẹkunrẹrẹ wa fun yin.

Ọjọ Aje ni wahala to n ṣẹlẹ lawọn ijọba ibilẹ nipinlẹ Oyo bẹyin yọ lẹyin ti eeyan kan dero ọrun lọjọ Aje nijọba ibilẹ Surulere, Irẹsaadu l'Ogbomoṣo.

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Isah Azeez lo gbẹmi mi nigba tawọn alatilẹyin awọn alaga ti wọn da duro kọlu awọn alatilẹyin awọn alaga afunsọ ti ijọba Gomina Seyi Makinde yan.

Ọgbẹni Azeez ni a gbọ pe wọn yinbọn pa nigba tawọn alatilẹyin awọn alaga ti wọn da duro, fẹ fipa le alaga afunsọ kuro lọfiisi rẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Gbenga Fadeyi ṣalaye pe, wọn gbe Azeez digbadigba lọ si ile iwosan Bowen l'Ogbomoṣo, amọ ẹpa ko boro mọ.

Ọpọ eeyan to mori bọ ninu iṣẹlẹ naa ni wọn farapa yanna-yannaa nibi ti wọn ti n sa asala fun ẹmi wọn.

Ija bẹ silẹ lẹyin tawọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC to lọ si ijọba ibilẹ Surulere lọsẹ to lọ, tun pada si ọfiisi ti wọn si ba alaga PDP ba nibẹ.

Ṣaaju rogbodiyan yii lawọn janduku ti dana sun ọkọ ati alupupu nijọba ibilẹ ariwa, guusu ati aarin gbungbun Ogbomoṣọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Fadeyi ṣalaye pe, awọn eeyan to fara gbọgbẹ si n gbatọju nile iwosan l'Ogbomoso.