Keke: Bayìí ni ìgboro Eko ṣe ri lẹ́yìn tri ìjọba fòfin de Keke àti Ọkada

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oní lọ́jọ́ pe ti ìjọba ìpínlẹ̀ Eko bẹ̀rẹ̀ òfin to fi de Keke àti Ọkada láwọ́n ìjọba ìbílẹ̀ kan jákejádo ìpínlẹ̀ Eko.

O jọ bi ẹni pe òfin náà fí ẹsẹ̀ múlẹ ti ìjọba si ti bẹ̀rẹ̀ si ni fi ọwọ ofin mú ẹnikẹni to ba kọ eti ọ̀gbọ̀in si àṣẹ ìjọba.

O han gedegbe pe lawọn agbegbe ti o ṣe pe ẹ o le rin diẹ lai ri ọkada tabi keke ti yoo gbe e yin lọ si ibikibi ti ẹ ba n lọ, gbogbo lo da paroparo.

Ẹ̀wẹ̀ Ọkàda àti Maruwa ṣi n síṣẹ ní àwọn ibòmiràn gẹ́gẹ́ oluranlọ́wa pàtaki Gomina Eko, Jubril Gawati ṣe sọ ọ nítori pé ìjọba ìbìlẹ mẹ́fa péré ninu ogun ni wọn ti fi ofin de wọn ti wọn si din ìrìn wọ́n kù ni àwọn ibomiran

Kódà, òfin náà mu gbogbo àwọn abani gbe ẹru ti wọ́n maa lo ọkada láti jísẹ, ọkan nínu àwọn ti wọ́n fi ọwọ òfin mu ni òwúrọ yìí rèé.

Ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé ìpínlẹ Eko lo ti n rọ ìjọba láti wá ọ̀nà abáyọ míràn si ìfòfin de Ọkada àti kẹkẹ Maruwa laarin igboro Eko.

Fọ́nrán kàn to gba orí àtẹjiṣẹ Twitter sàfihan àwọn ọkọ ajagbe kan to n di ẹru kẹkẹ àti ọkada ti wọ́n n ko kuro ní ìlú Eko, pàápaàá jùlọ ni àgbègbè Oniru.

Bakan náà ni àwọn olugbé ìpínlẹ̀ Eko sọ ìríri wọ́n lónìí ti òfin náà fidi múlẹ̀.

Alàye Gomina Sanwo-Olu lori idi ti wọ́n fi fi òfin de Okada àti Maruwa rèé lásìkò to n dáhun ìbere láti ọdọ àwọn àkẹkọọ ile Eko kan nilu Eko to sàbẹ̀wò si i ni ọfiisi rẹ.

Sanwo-Olu ni pé ijọba ibilẹ mẹẹdogun ni àwọn ti fofin de ninu ìjọba ibilẹ ogun àti àgbegbe idagbasoke mẹ́tàdinlógójì to wà nippinlẹ Eko,

O salaye pe nibomiran ẹwẹ, àwọn no ki wọ́n maa rin sùgbọ́n wọ́n ko gbọdọ gun ori afara ni.