World Hijab Day: Ọmọ Musulumi tí orin takasufèé rẹ̀ ta lẹ́nu rèé

Ninu fidio to wa loke yii, awọn orin ti Mina Voilée n kọ kọja afẹnusọ gẹgẹ bi olorin takasufee ṣugbọn to n ri idiwọ lati ọdọ gbogbo awọn to yi i ka.

"Wọ́n sọ fún mi pé nkò lè lo Hijab ki n tun maa kọ orin takasufee, wọ́n maa ń pè mí ni Eṣu pe mo ti ba ẹsin jẹ"

Ni idile ti wọn ti bi Mina gẹgẹ bii ọmọ Musulumi, o ni awọn ko le jade ki wọn ṣi wa nita di ago meje alẹ, ko ṣeeṣe. Lati kekere ni Mina si ti n wọ Hijab.

Mina ni ohun ti oun nṣe ko ye gbogbo awọn to n bu oun lori ayelujara ni wọn ṣe n sọrọ bẹẹ.

"Wọ́n sọ fún mi pé nkò lè lo Hijab ki n tun maa kọ orin takasufee, wọn ní mò ń ba ẹ̀sìn jẹ́".

Koda Mina ni baba rẹ kọjalẹ nigba ti ọrọ yii kọkọ bẹrẹ ṣugbọn nigba ti wọ ri i pe oun ti ọkan oun fẹ ṣe niyẹn, wọn pada bẹrẹ si ni ti i lẹyin.

"Gbogbo igbiyanju wọn lati jẹ ki n fi i silẹ ni mo kọ. Lati igba naa ni wọn ti n ti mi lẹyin" ti Mina fi le sọ wi pe "Hijab mi ni idanimọ mi"