Toyosi Adesanya: 'Ọ̀kọ̀ wa wọ'gbó lọ lẹ́yìn táwọn dánàdánà dàbọn bò wá'

Gbajugbaja osere tiata lobinrin, ti ori ko yọ ninu ijamba ọkọ lọjọ Aje, Toyosi Adesanya Ilesanmi ti salaye lẹkunrẹrẹ nipa bi isẹlẹ to mu ẹmi awakọ rẹ, Juwọn Awẹ, se waye.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ laarọ ọjọbọ, Toyosi ni awakọ oun, Juwọn ati awọn eeyan mẹrin miran lawọn jọ wa ninu ọkọ, lati lọ se ere tiata kan nilu Ilọrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni bi awọn se fẹ wọ ilu Ilọrin lawọn n gbọ "Fulani Herdsmen! Fulani Herds men!", ti gende agbebọn mẹrin, Fulani mẹta ati Yoruba kan si sadede bọ soju ọna, ti wọn si ni ki awọn duro.

O fikun pe Juwọn to wa ọkọ lo fi aake kọri lati duro, ti oun si n kilọ fun pe ko ma sa fun wọn, amọ ko gbọ, to si sare kọja awọn agbebọn ọhun, eyi to mu ki wọn yinbọn fun awọn.

O ni bi mọto awọn se wọnu igbo lọ ree, tawọn agbebọn naa si ja awọn lole, wọn tu gbogbo ẹru awọn, ti wọn si gba owo ati ẹrọ ibaraẹnisọrọ awọn, ti oun ko si lee sọ ipo ti oun wa, bẹẹ ni Juwọn ti dero ọrun.

Nigba to n sọrọ lori bi Juwọn se de ọdọ rẹ, o ni oloogbe naa bẹrẹ isẹ ni ọdọ oun ni ọjọ Keji osu Kinni ọdun 2020, amọ o ti n sisẹ ni ọdọ awọn akẹẹgbẹ oun ninu isẹ tiata tẹlẹ, ti wọn jọ ni ede aiyede eyi ti ko jẹ ki oun fẹ kọkọ gbaa mọra.

"Se ni Juwọn de ile mi nilu Akurẹ lọjọ keji osu kinni yii, to si n bẹ mi pe ki n se aanu oun. Mo sọ fun pe ko lọ pari ija pẹlu awọn to ni ikunsinu pẹlu rẹ amọ o sa n bẹ mi ni. Niwọn igba to si jẹ pe ara awọn eeyan kan naa ni emi naa ti dide, lo jẹ ki n faa mọra."

"Mo sẹsẹ ra ẹrọ ibaraẹnisọrọ tuntun fun ni, to si bẹrẹ idanilẹkọ nipa ere tiata. Igba ta fẹ lọ sisẹ nilu Ilọrin lo ni oun yoo tẹ le wa lọ nitori ilọrin lo ti se kekere, to si fẹ ri awọn eeyan to ti ri tipẹ."

Toyosi, nigba to n sọ iru eeyan ti oloogbe ọhun jẹ nigba aye rẹ salaye pe eeyan daada ni, kii bẹru tabi foya, to si ni iwa irẹlẹ pupọ.

"Lẹyin to de ọdọ mi tan ni mo wa ri pe oloogbe Juwọn naa fẹran obinrin, igba to ku tan yii ni mo gbọ pe obinrin marun lo ti bimọ fun. Sugbọn lọdọ temi, ọmọ daada ni nitori ko si si ẹni ti ko ni aleebu tiẹ lara."

Ilumọọka osere tiata naa ni oloogbe ọhun maa n ba oun fọ asọ, to si maa n ba gbogbo eeyan sere. Ko si si ibi to de, ti kii fẹ ki awọn eeyan to wa nibẹ sakiyesi oun.

"Juwọn ni igboya, ti mo si maa n sọ fun pe igboya rẹ ti pọ ju, gbogbo igba si lo maa n se adura pe asiko ti oun wa lọdọ mi yii ni oun maa jẹ eeyan, ti gbogbo wa yoo si maa rẹrin."

Toyosi wa dupẹ pupọ lọwọ gbogbo eeyan to dide fun iranwọ rẹ lasiko ti isẹlẹ naa waye, paapa awọn asaaju ẹgbẹ osere tiata TANPAN, ti Bolaji Amusan, taa mọ si Mr Latin ko sodi ati Alhaji Abbey Lanre.

Bakan naa lo n dupẹ lọwọ Ọmọọba Jide Kosọkọ, Adebayọ Salami taa mọ si ọga Bello, to pe lati ilu ọba, ati gbogbo ọmọ ẹgbẹ Tanpan, ẹka tipinlẹ Kwara, ti gbogbo wọn ko fi silẹ, lasiko isẹlẹ naa, paapa alaga Tanpan Kwara, ti wọn n pe ni 'Akinkanju ọdẹ Ilọrin'.

"Mo ni aarẹ ẹgbẹ to dara ninu ẹgbẹ Tanpan, Bolaji Martins Amusan, mo si jẹ anfaani pe mo n se ẹgbẹ naa, mo mọ koko pe mo n se ẹgbẹ, mo si tẹle asaaju to dara, oun ati Abbey Lanre, isẹlẹ yii si jẹ ki n mọ bi mo se tobi to laarin awọn akẹẹgbẹ mi ati awujọ wa lapapọ."

"Awa la se awọn nkan to pọ lati sin oloogbe, ti awọn ẹbi rẹ naa si fọwọsowọpọ pẹlu wa. Awọn eeyan kan gbogun, amọ awọn ẹbi oloogbe dide pe awọn ti ri gbogbo ohun to sẹlẹ ni Ilọrin awọn ko si fa wahala kankan bikose ki gbogbo wa dijọ pawọpọ lati tọ awọn ọmọ to wa nilẹ."

Nigba to n sọrọ lori ẹkọ ti isẹlẹ naa kọ, Toyosi ni ko si ohunkohun nile aye yii, ka ma si se sababi iku.

"O yẹ ka maa ronu pe iku lee de nigba kuugba, Ọlọrun lo kan yọ awa naa, tori Fulani kii kọlu eeyan, ko ma ku. Ka maa gbadura."

Bakan naa lo gbadura pe ki Ọlọrun fun wa ni eto aabo Amotekun se nilẹ Yoruba nitori ko si eto aabo tabi olugbeja fun wa rara, Ọlọrun nikan ati awa ara wa la n daabo bo ara wa, yoo si dara ki ijọba saanu wa.