You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ogun robbery: Ọlọ́pàá ní àwọn afurasí adigunjalè náà ló ń ṣe ọṣẹ́ ní Abeokuta
Babalawo kan ati awọn afurasi adigunjale marun miran, to maa n da awọn eeyan agbegbe Osiele nilu Abeokuta riboribo, ni ọwọ palaba wọn ti segi.
Osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo kede aseyọri yii ninu atẹjade kan to fisita lọjọ Aje.
Oyeyemi ni awọn eeyan lo ta ikọ ọlọpaa to n gbogun tiwa idigunjale SARS lolobo nipa irinsi awọn afurasi naa ati ibuba wọn to wa lagbegbe Odeda.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Agolo gáásì kéeké tó ń jò bú gbàmù l‘Eko, ẹ̀mí kan bọ́, mẹ́ta fara pa
- Aàrẹ Buhari buwọlu yíyí orùkó àwọn ibùdókọ ọkọ ojú ìrìn bíi ti Apapa padà fi sọrí àwọn èèkàn ìlú
- 'kò sí ẹ̀rí àrídájú níńu ọ̀rọ̀ Akpabio'
- Ìyá òòṣà fẹ̀sùn àjẹ́ kan ìyá ẹni ọdún 90, aráàlú bá sọ ọ́ lókò pa
- Nàìjíríà ṣí àwọn ilé ìwé padà; Ìdánwò WAEC á bẹrẹ lẹyìn ọdún Iléyá!
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
"Ni kete ti wọn ta awọn ọlọpaa SARS lolobo ni wọn ya bo adugbo naa, ti ọwọ si tẹ afurasi adigunjale mẹrin.
Ọrọ ti wọn sọ si lo jẹ ki ọwọ tẹ babalawo ti wọn lo jẹ baba isalẹ wọn, to maa n ro wọn lagbara nigba kuugba ti wọn ba n lọ sisẹ idigunjale, tabi gba ọmọ ẹgbẹ tuntun sagbo wọn."
Alarina ọlọpaa fikun pe lara awọn ohun ti wọn gba lọwọ awọn adigunjale naa ni ibọn agbelẹrọ labẹle, aake, ọbẹ meji ati oniruuru oogun abẹnu gọngọ.
O wa fikun pe Kọmisana ọlọpaa fun ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti pasẹ pe ki wọn se ẹkunrẹrẹ iwadii nipa awọn afurasi naa.
Géndé ọkùnrin mẹ́ta gba ìdájọ́ ikú fún ẹ̀sùn ìdigunjalè l'Ọṣun
Gende ọkunrin mẹta ti gba idajọ iku nipa yiyẹ igi fun wọn nile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Ọṣun.
Onidajọ Jide Falola ti ile ẹjọ giga naa to wa ni ilu Ikirun sọ pe awọn mẹtẹẹta, Nuhu Jimoh, Ndubisi David ati Aderibigbe Oluwaseun, jẹbi ẹsun jija banki mẹta l'ole nilu Ikirun l'ọdun 2016.
Awọn ọkunrin naa ni wọn sọ pe wọn wa lara ikọ adigunjale to fi nnkan abugbamu fọ ilẹkun awọn banki mẹta ọhun, ki wọn o to ja wọn lole.
Ṣugbọn, ọrọ bẹyin yọ fun wọn nigba ti awọn ọlọpaa dena de wọn, ki wọn o maa ba ri owo ti wọn jiko gbe lọ.
- "Oṣù yìí ni Juwọn bẹ̀rẹ̀ sí ní bá mi ṣiṣẹ́ kó tó ṣàgbákò ikú òjijì"
- Ọ̀gá ọlọ́pàá tó wà ní 'Check Point' kàgbákò ikú òjijì lọ́wọ́ awakọ̀ l'Eko
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ń gbé láti dènà ààrùn coronavirus ní Nàìjíríà
- Iná tún ti jó ilégbèé àwọn obìnrin níléẹ̀kọ́ Poly Ẹdẹ, dúkìá ₦10m ṣòfò
- Ọgbẹ́ ọkàn láéláé ni fún ọmọbìnrin ọdún mẹ́wàá, tí bàbá rẹ̀ dáná sí lábẹ́ - Amòfin
- "Mo lu òyìnbó ní jìbìtì $82, 570 lóríí ayélujára, ìyá mi ló bá mi fi owó náà ra ilé"
Iroyin sọ pe ọpọlọpọ araalu ati ọlọpaa meji lo padanu ẹmi wọn lasiko ti awọn adigunjale naa ati awọn ọlọpaa kọju ija ibọn sira wọn.
Ẹsun mẹta to ni i ṣe pẹlu ole jija, ipaniyan ati nini nkan ija oloro lọna aitọ ni wọn fi kan wọn.
Bakan naa ni a gbọ pe ibọn ọlọpaa ran diẹ lara awọn adigunjale naa lọ sọrun, ti awọn yooku wọn si salọ.
Onidajọ Falola dajọ pe ki wọn o yẹgi fun awọn mẹtẹẹta titi ti ẹmi yoo fi bọ l'ẹnu wọn, to si tun paṣẹ pe ki awọn ibọn ti ileeṣẹ ọlọpaa gba lọwọ wọn o di ti ileeṣẹ ọlọpaa, ki owo ti wọn gba lọwọ wọn o si di ti ijọba ipinlẹ Ọṣun.