You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ede Poly Fire: Igbó tí wọn ń ṣun ládùgbóò ló fa ìjàmbá iná
Ijamba ina tun ti waye nilegbe awọn obinrin to wa lọgba ileẹkọ poly tilu Ẹdẹ.
Gẹgẹ bi ileesẹ panapana nipinlẹ Ọsun ti salaye, aarọ ọjọbọ ni isẹlẹ ina ọhun waye nitori igbo kan ti wọn n sun ladugbo Jere ti ilegbe awọn obinrin naa wa.
Wọn fikun pe ina ọhun ni ọwọja rẹ tan lati adugbo wọ inu ọgba ileeẹkọ Poly naa, to si se ọsẹ nla ọhun.
- Àgbékalẹ̀ Amotekun dára torí agbára òògùn àwọn baba wa kò dínkù tàbí parẹ́ - Peter Fatomilola
- Owó ìjọba ìbílẹ̀ ló wọ àwọn alága káńṣù APC lójú l‘Ọyọ - Seyi Makinde
- Abaribe, ọ̀rọ̀ agọ̀ lo sọ pé kí Buhari kọ́we fipo sílẹ́ torí ààbò tó mẹ́hẹ - Iléèṣẹ ààrẹ
- Àlárùn Coronavirus di 7000 lágbàyéé, ìjọba Nàíjíríà kọjú oro sí ọjà China tó jẹ́ ẹbu
- Ọ̀rọ̀ owó lo da emi àti Saheed Balogun pọ ti mo fi ke gbajare lori Instagram-Sotayogaga
Ilegbe ọhun, ti wọn ko tii kọ pari, ni ina ọhun jo kanlẹ, ti ko si si ẹmi kankan to ba isẹlẹ naa rin.
Nigba to n se akojọ apapọ iye ti awọn dukia to jona yoo to, awọn osisẹ panapan naa ni o kere tan iye dukia to jona ninu isẹlẹ naa yoo wọ miliọnu mẹwa naira.
Nigba to n fidi isẹlẹ yii mulẹ, awọn agba osisẹ kan lọgba Poly Ẹdẹ naa salaye pe awọn eeyan kan to n sun igbo, eyi ti ọwọja rẹ tan de inu ọgba awọn, tawọn si tete ke si ileesẹ panapana.
Wọn wa kan saara sileesẹ panpana ipinlẹ Ọsun fun bo se tete dahun si ipe awọn, eyi to mu adinku ba ọwọja itankalẹ ina naa.