You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Falz f'ohùn lẹ̀ fún PDP, APC, MURIC, àwọn ọmọ Yahoo
Gbajugbaja olorin nni, Folarin Falana ti gbogbo eniyan mọ si Falz tun ti gbe iṣe rẹ de pẹlu orin bi owe bi owe rẹ̀.
Eyi to ṣẹ tun gbe jade ni fidio orin to kọ lati fi sọ oko ọrọ si awọn ẹgbẹ tabi ọlọdani lawujọ.
Lara wọn ni ẹgbẹ oṣelu PDP, APC, ẹgbẹ MURIC, àwọn obinrin oloṣo, àwọn ọmọ Yahoo atawọn oloṣelu lapapọ.
Ninu eyi to wa ninu awo to ṣẹṣẹ gbe jade, 'Moral instruction', Falz tẹnu mọ awọn iṣoro to n koju awọn eniyan orilẹede yii.
Ko tilẹ fi akoko ṣofo rara pẹlu ọrọ oko rẹ to kọkọ ju to sọ wi pe "Brother Muri shout finish, we no see am for court",
eyi lo fi n ba ẹgbẹ to nja fun ẹtọ awọn musulumi (MURIC) to ni awọn yoo gbe lọ ile ẹjọnitori orin rẹ, "This is Nigeria" nibi to ti lo awọn ọmọbinrin to lo Hijab.
Ẹwẹ, titi di igba to gbe orin mii tuntun sita, ẹgbẹ MURIC ko tii gbe e lọ ile ẹjọ.
Falz tun mẹnu ba ọrọ awọn oloṣelu to ma n rinrinajo lọ oke okun loore koore, nipa ipolongo idibo, nipa awọn ọmọ Yahoo Yahoo, awọn ọmọ oloṣo ati igbe aye olowo gee gee tawọn pasitọ kan n gbe.
Gẹgẹ bi alaye, ohun ti fidio orin Falz n sọ ni pe "a ti de ibi ti to yẹ ka ti yi iwa pada si ara wa ki a si mọ ohun to tọ yatọ si eyi ti ko tọ.
Fun Falz, eyi nikan lo le mu nkan pada bọ sipo.
O ni, "#Talk, o ṣe pataki fun wa lati maa sọrọ sita. A o le ri ojutuu bi a ba n dakẹ, ki t'ara wa ma ba wa dakẹ. A ni lati fesi! Nisinsiyii!"
Ẹwẹ, lori ẹrọ ayelujara, awọn ololufẹ FalZ ti bẹrẹ si ni da si ọrọ nipa orin naa ati fidio rẹ.
Falz ni oun sọ ohun gbogbo to yẹ ki ẹ mọ nipa iṣejọba Aarẹ Buhari ninu fidio oni iṣẹju mẹta o le iṣẹju aaya mejidinlọgbọn.
O ni ootọ maa n dun eniyan ṣugbọn ẹnikan ni lati sọ ọ .
Falz tun fi ara rẹ we Fela nigba aye rẹ, didojukọ ijọba. Wọn n pe e ni ẹṣin iwaju sibẹ o n mu igbo o si n kọrin nipa ẹya ara.