You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Níbo láyé kọjú sí: Kí ni ohun àmúyẹ tí ò ń wa lára ẹni tí o fẹ́ fẹ́?
Àwọn alejo lori eto 'Níbo láyé kọjú' ti BBC Yoruba jẹ ko di mimọ pe ibi ti o ba kọ si onikaluku ni yoo fi mọ ohun ti o fẹ lara ẹni ti o ba fẹ fẹ.
Ni ti Ọgbni Olasunkami Arowolo to jẹ olukọ ile iwe giga fasiti, obinrin teeyan o fẹ sile gbudọ ni ibọwọ, suuru, iwa eyi to ṣe koko.
Arabinrin Yetunde Olawale jẹ onimọ ofin ati aṣoju loge, o jẹ ko di mimọ pe ọpọ ọkunrin lo maa n diju si ojuṣe wọn gẹgẹ bi ọkọ. o ni atọkunri ati obinrin lo y ko ni suuru.
Lilọ mọ obi ẹni ti o fẹ fẹ ṣe pataki gẹgẹ bi Yetunde ṣe sọ ọ lodi si bi awn ọmọ aye isnsiyii ṣe n ṣe lai fi to obi wọn leti debi ti wn yoo ṣewadi lẹkunrẹrẹ.
Yetunde tẹnu mọ ọ pe "ko si iyatọ ninu ọkunrin olootọ ati eyi ti ko sootọ mọ"
Awọn mejeeji fẹnu ko wi pe o da lori adehun ti awọn mejeeji ba ṣe ki wọn to bẹrẹ si ni gbe gẹgẹ bii lọkọ laya.
Ẹwẹ, bi eto naa ṣe nlọ ni awọn to n wo o nile naa n fi iha ti o kọ si wọn ṣọwọ loju opo facebook bbcnewsyoruba.
'Ọkùnrin tí kò bá sanwó iléèwé ọmọ, kó lọ wẹrí'
Ọkan lara awọn alejo ninu abala mii lori eto 'Níbo láyé kọjú' tẹnu mọ ọ pe ọkunrin ti ko ba le san owo ile iwe ọmọ n ta ibukun rẹ ni.
Gẹgẹ bi awọn ọmọ ile iwe ṣe n mura ati wọle sẹnu ẹkọ wọn pada eyi to ja si pe awọn obi gaan ku igbaradi lati san owo ile iwe tuntun, o ru ifọrọwerọ jade lori ta lo yẹ ko maa san owo ile iwe.
Arabinrin Adebiyi Adepeju ni o yẹ ki ọkọ gidi da owo ile iwe pada tori kii ṣe ẹtọ iya, ẹtọ baba ni.
O ran wa leti aye atijọ pe awọn iya wa a maa wa ninu ile fun itọju ile ati ara ile bẹẹ si ni ọkunrin kii fi iṣẹ tirẹ silẹ.
"Aye ode oni, ọgbọọgba ni wọ́n fẹ́ máa pin iṣẹ; ida aadọta si aadọta ni wọn fi n ṣe ninu ọgọrun".
Ni idakeji, arabinrin Ọlawale Ọnabajo lòdì sí koko ọrọ arabinrin Adepeju pe ọkunrin ni ko maa san owo ile iwe awọn ọmọ wọn.
O ni ninu ile ti ifẹ ba wa, ko si nkankan to jẹ pe wọn gbe ori ọkurin fun alagbafọ. O ni o yẹ ki ifẹ wa ninu ile ki wọn si tori eyi fi mọ awọn ọmọ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe arabinrin Adebiyi ni ọpọlọpọ igba ti obinrin ba da si sisan owo ile iwe ọmọ, o n furugbin si ọjọ la rẹ ati tawọn ọmọ ni.
Arabinri Adepeju daa pada pe bi obinrin ba tilẹ ran ọkọ rẹ lọwọ lati san owo ile iwe, o yẹ ki ọkọ daa pada nitori ọp ọkunrin lo maa n sọ ọ di oju ọwọ. O ni lootọ, awọn nkan mii le ṣẹlọ ti obinrin yoo fi san owo ile iwe awọn ọmọ ṣugbọn kii ṣe ẹtọ ẹ.
Ẹwẹ, loju opo facebook https://www.facebook.com/bbcnewsyoruba/videos/511269552612226/ ti fidio naa wa, ọpọlọpọ awọn to wo eto naa lo da si koko ọrọ yii pe "ṣe o yẹ ki obinrin maa san owo ile iwe ọmọ?