Kí gan an ni ẹgbẹ́ NURTW ní ṣe pẹ̀lú òṣèlú Nàìjíríà?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Fun igba pipẹ, ẹgbẹ awakọ eero, National Union of Road Transport Workers, NURTW, ni ẹkùn Iwọ oorun Gusu Naijiria, maa n ko ipa to lapẹrẹ lasiko ti eto idibo ba waye.

Ni ọpọlọpọ igba ti wahala ba ṣẹlẹ nibi ipolongo ibo, tabi eto idibo, 'ko wọ pọ ki awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW ma ba wọn kopa ninu rẹ.'

Eyi ṣi ṣeeṣe ko jẹ nitori 'wọn maa n wa ni imurasilẹ tabi finufindọ sẹtan lati yọnda ara wọn lati da wahala silẹ, ti ẹgbẹ oṣelu to ba wa nipo si maa n 'wa ojurere wọn.'

Awọn iṣẹlẹ kan to ti waye ni awọn ipinlẹ bi Ọyọ, Ondo, Ekiti ati Eko n tọka si i pe ipa ti ẹgbẹ NURTW n ko ko kere ninu eto oṣelu.

Ọkan to wa si iranti ni iṣẹlẹ to waye ni ọgbọnjọ, oṣu Kejila ọdun 2010, niluu Ibadan lasiko ti ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), ṣe ipade ita gbangba ẹgbẹ naa ni imura silẹ fun eto idibo ọdun 2011.

Ipade oṣelu ọhun yọri si wahala ati itajẹsilẹ. Koda, wahala naa lo yọri si iku olori igun kan ninu ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Ọyọ, Lateef Salakọ (Eleweọmọ), ati bi awọn ọlọpaa ṣe gbe Olori ile aṣofin agba nigba naa, Sẹnetọ Teslim Fọlarin ti wọn fi ẹsun kan pe o mọ nipa bi wọn ṣe ṣekupa Eleweọmọ.

Lasiko naa, igun meji lo wa ninu ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọyọ ati NURTW. Igun akọkọ ni ti Sẹnetọ Teslim Fọlarin/Rasheed Ladọja to fi igba kan jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ. Igun yii ni ibaṣepọ pẹlu igun ti Lateef Akinṣọla (Tokyo) n dari ninu NURTW.

Bakan naa ni igun PDP ti gomina ipinlẹ Ọyọ nigba naa, Alao Akala ati Eleweọmọ.

Ṣaaju asiko yii ni Tokyo ati Eleweọmọ ti n ja si ipo alaga ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Ọyọ.

Iṣẹlẹ mi i ti ko tun ṣe e gbagbe ni eyi to waye nipinlẹ Ondo lasiko ti awọn janduku ti igbagbọ wa pe ọmọ ẹgbẹ NURTW ni wọn ya bo ipade itagbangba ti ẹgbẹ oṣelu APC se loṣu Kẹwa ọdun 2018, ti wọn si lu awọn to dibo yan Idowu Otetubi sipo alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ naa. Wọn tilẹ ja aṣofin to n ṣoju ijọba ibilẹ Idanre/Ifẹdọrẹ Federal Constituency, Baderinwa Bamidele, si ihoho.

Iṣẹlẹ to tun jọ eyi ni asiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW yabo ile aṣofin ipinlẹ naa pẹlu afojusun lati da ijiroro iyọni nipo ru lọjọ kẹsan, oṣu Kọkanla ọdun 2018.

Ṣaaju ọjọ naa ni ede aiyede ti nwaye nile aṣofin naa nipa awọn adari wọn, ti aṣofin mejidinlogun ninu mẹrindinlọgbọn si yọ adari ile, Bamidele Oleyelogun ati igbakeji rẹ, Ogundeju Iroju nipo fun ẹsun aṣilo ipo.

Awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ ọhun kọ oju ija si awọn aṣofin, awọn oniroyin, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ile aṣofin.

Awọn iroyin kan tilẹ sọ wi pe ikọlu naa ko ṣẹyin awọn alaṣẹ ẹgbẹ APC nipinlẹ naa, to pe alaga ẹgbẹ NURTW, Adebo lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ lati lọ da ijoko ile ru, eyi to mu ki oun naa paṣẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ lati ṣe bẹẹ. Awọn nkan oloro bi ibọn, ada, aake, afọku igo, to fi mọ oogun abẹnu gọngọ ni wọn ko lọ sile asọfin.

Bo tilẹ jẹ wi pe ẹgbẹ NURTW sọ ni gbangba pe 'ohun lo n wa nidi ikọlu naa, ko daju pe ileeṣẹ ọlọpaa gbe igbesẹ to lagbara lori rẹ.'

Bakan naa ni ipinlẹ Ekiti, niṣe ni awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW kọju ija sira wọn, ti igun kan si gbiyanju lati le awọn kan kuro lori oye ni kete ti wọn kede gomina Kayọde Fayẹmi gẹgẹ bi ẹni to bori ninu idibo sipo gomina to waye nipinlẹ naa lọjọ kẹrinla, oṣu Keje ọdun 2018.

Awọn igun kan gbagbọ pe o yẹ ki awọn oloye ẹgbẹ lasiko naa 'faramọ iṣejọba gomina ana, Ayọdele Fayoṣe, o si yẹ ki wọn o fi ipo silẹ fun awọn to faramọ Kayọde Fayẹmi'.

Eyi ti ko to waye laipẹ yii ni wahala to waye nibi ipolongo ibo ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Eko lọjọ kẹjọ, oṣu Kejila 2018.

Ipolongo ibo ọhun ti oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ APC, Babajide Sanwo-Olu fi ṣide ipolongo rẹ, lo pari pẹlu wahala lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW da wahala silẹ.

Iṣẹlẹ naa fa ifarapa fun awọn oniroyin, ọmọ ẹgbẹ APC, to fi mọ ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ NURTW, Musiliu Akinsanya (MC Oluọmọ) to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC.

Iroyin fidirẹ mulẹ pe ṣeni awọn janduku naa n yinbọn laibikita, ti ibọn naa si ba akọroyin mẹta. Bakan naa ni wọn fi ọbẹ gun MC Oluọmọ, ti gbogbo wọn si di eero ileewosan.

Lootọ, gbogbo ọmọ Naijiria lo lẹtọ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to ba wu u, ṣugbọn ibeere to ṣaba maa n wa si ọkan nipe, ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ NURTW n darapọ mọ oṣelu nitori pe wọn fẹ jẹ ọmọ ẹgbẹ ni tabi nitori nkan ti awọn oloṣelu n lo wọn fun lasiko eto idibo?

Awọn ololufẹ BBC Yoruba sọ ero ọkan wọn lori eyi.