You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Catholic protest: Ìjọ Aguda ṣèwọ́de l'Abuja, ó ní àwáwí ìjọba ṣú òun lórí ààbò tó mẹ́hẹ
Yoruba ni agba ti ko ba kẹhun sọrọ, afaimọ ko ma kẹtan sare, idi ree ti awọn ọmọ ijọ Aguda fi tu jade kẹti-kẹti nilu Abuja lọjọ Aiku, lati ṣe iwọde tako awọn iṣẹlẹ iṣekupani to n waye ni Naijiria.
Ẹgbẹ awọn biṣọpu ijọ naa to se agbatẹru iwọde ọhun sọ pe, ijọba ko ṣe to lati daabo bo ẹmi awọn araalu, ti awawi rẹ pe, oun ti sẹ eegun ẹyin ikọ asẹrubalu Boko Haram, si ti su awọn.
Aṣọ dudu ni awọn to wọde naa wọ, eyi to tumọ si pe asiko ọfọ tabi ibanujẹ ni akoko naa jẹ fun wọn.
Awọn alaṣẹ ijọ naa sọ pe, iwọde naa waye lati gbadura ati lati bẹbẹ fun alaafia ati aabo ni orilẹ-ede Naijiria.
"Iwa ika gbaa ni ka pa eniyan, bẹẹ si ni kikuna lati daabo bo ẹmi alaisẹ lọwọ iku aitọjọ gan, iwa ika ni. Ọpọ isinku apapọ lo n waye ni Naijiria, ijinigbe awọn arinrinajo ati ọmọ wẹwẹ to fi mọ ikọlu awọn eeyan ninu ile wọn, sọọsi, mọsalasi ati ileẹkọ oniwaasu."
Bẹẹ ba gbagbe, o ti to bi igba melo kan ti awọn ajinigbe ti ji awọn alufaa ijọ Aguda gbe, ti ijọ naa si sọ pe, awọn kan gba ominira lẹyin ti ijọ san owo. Ṣugbọn, awọn ajinigbe pa awọn kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari,nígbà wò ló fẹ́ bá ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ nípa Coronavirus-PDP
- Ìtàn ayé Taiwo Oredein rèé, àgbà òṣèlú tó parí ayé rẹ̀ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Pa Kasumu,gbajúgbajà òṣèré tíátà Yorùbá jáde láyé
- Ó dá mi lójú pé ọmọ ìjọ mi kò lé è kó àrùn Coronavirus - Adeboye
- Èdè àìyedè bẹ̀rẹ̀ lórí bí àgbélẹ̀rọ òyìnbó Nàíjíríà ṣe wọ ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì Oxford
- Ògbólógbòó ìjàpá rèé, tó bí ọmọ 800 kí ìran rẹ̀ má ba à parun
Oṣu Keji ni awọn ajinigbe tun pa ọkan lara awọn akẹkọọ Alufaa ijọ naa nipinlẹ Kaduna, Michael Nnadi, lẹyin ti wọn ti ji gbe fun igba diẹ.
Ẹni ọdun mejidinlogun ni.
Laipẹ yii naa ni ijọ irapada Kristi, Redeemed Christian Church of God, naa ṣe iwọde lati tako ipaniyan ni orilẹ-ede Naijiria.