You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oxford Dictionary: Àwọn òǹkọ̀wé kan ní ìtàbùkù ojúlówó èdè òyìnbó ní ìgbésẹ̀ náà
Laipẹ yii ni wọn fi awọn ede oyinbo ti awọn ọmọ Naijiria se agbelẹrọ rẹ sinu iwe atumọ ede Gẹẹsi lagbaye, Oxford English Dictionary (OED), amọ awuyewuye si tun n lọ lori awọn ohun to yẹ ko jẹ ojulowo ede oyinbo tootọ.
Tẹlẹtẹlẹ lawọn eeyan to sọ ara wọn di ọlọpa fun ede Gẹẹsi, maa n foju tẹnbẹlu awọn ede oyinbo kan taa maa n sọ ni Naijiria, amọ nibayii, tawọn ede oyinbo yii ti wọnu iwe atumọ ede Gẹẹsi, a jẹ pe a ti ri nkan tọkasi, ti wọn ba tun tako oyinbo ta sọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ògbólógbòó ìjàpá rèé, tó bí ọmọ 800 kí ìran rẹ̀ má ba à parun
- Buhari o, tètè ṣètò àtúntò Nàíjíríà ká le è dènà ogun abẹ́lé lẹ́ẹ̀kejì - Obasanjo figbe bọnu
- Nàíjíríà, ẹ wo bí àwọn ìlú ńlá-ńlá ṣe ń dènà ìtànkálẹ̀ Coronavirus, ẹ fi ṣe àwòkọ́ṣe
- Onínúfùfù ni Saheed Oṣupa, ṣùgbọ́n èèyàn dáradára ni-Taye Currency
Ede oyinbo ta se agbelẹrọ wọn ni Naijiria to to mọkandinlọgbọn niye, ni wọn fi sinu iwe ede atumọ naa, eyi ti wọn lo se afihan pe ede oyinbo ti di itẹwọgba jakejado agbaye ati ni orilẹede to tobi julọ nilẹ Afirika.
Sugbọn ni bayii, igbesẹ fifi awọn ede oyinbo ti Naijiria se agbelẹrọ rẹ yii sinu iwe atumọ ede Gẹẹsi, tun ti mu ọpọ awuyewuye miran dani, ti ero awọn eeyan si se ọtọọtọ nipa igbesẹ naa.
Lero tawọn eeyan kan, ko si ohun to kan awọn nipa ero awọn oyinbo Gẹẹsi lori bi oyinbo Naijiria se wọnu iwe atumọ ede oyinbo wọn, nitori ọpọ awọn ede oyinbo kan ni igba ti lọ lori wọn.
Bakan naa ni isọri awọn eeyan miran ti n fi apa janu pe, ko daa bi wọn se fi ede ọmọ ita, ede gọta ta n sọ ni Naijiria bii ede oyinbo, sinu iwe atumọ ede Gẹẹsi.
Nigba to n sọrọ lori iyapa ero nipa ede oyinbo naa, Uzoh Nwamara, tii se alaga ẹgbẹ awọn onkọwe labẹle salaye pe ohun tawọn n reti tẹlẹ ni pe ki wọn sọ ede Pigin, taa mọ si amulumala oyinbo di itẹwọgba lagbaye nitori o ti tan kalẹ de ọpọ orilẹede, to si ti di itẹwọgba lawọn orilẹede ti wọn ti n sọ oyinbo ati Faranse.
Koda, o ni bi ileesẹ BBC gan se da ẹka kan silẹ to n gbe iroyin jade ni ede Pidgin ti fihan pe ede naa ti di itẹwọgba pẹlu afikun pe bi wọn se fi ede Pidgin silẹ, lọ maa tọwọbọ ede oyinbo to ko wa lẹru ko dara rara, to si pose.
Bakan naa ni Onpitan kan ni Naijiria, Timi Soleye salaye pe, iwe atumọ ede Gẹẹsi ti kọja aye rẹ, to si ti se ohun ti ko yẹ nidi ilakaka rẹ lati tan iyẹ kaakiri.
O afikun pe ko si ohun to buru ti wọn ba fi awọn ọrọ orukọ to ti di itẹwọgba sinu iwe atumọ ede Gẹẹsi naa, amọ o ni ko yẹ ki wọn fi awọn ọrọ ise kankan sinu rẹ.
"Igbesẹ naa dabi igba ta mọmọ fọwọsi itabuku ede oyinbo, awọn eeyan lee maa sọ amulumala ede oyinbo taa n pe ni Pidgin, amọ o yẹ ko ye wa daju pe, kii se ede oyinbo tootọ ni wọn n sọ, ko si yẹ ka sọ di ojulowo ede oyinbo."
Sugbọn ero ti onkọwe kan ni Naijiria, Eghosa Imasuen yatọ si eyi. O ni tori wọn fi awọn oyinbo Naijiria kan sinu iwe atumọ ede ko tumọ si pe awọn eeyan ko maa sọ awọn ede naa tẹlẹ.
Bakan naa ni Kingsley Ugwuanyi, to jẹ ọmọ Naijiria to n sisẹ pẹlu ileesẹ to n se iwe atumọ ede Gẹẹsi sọ fun BBC pe, ọpọ oyinbo ti a se agbelẹrọ rẹ ni Naijiria ni yoo tun wọnu iwe atumọ ede Gẹẹsi ti Oxford laipẹ yii.
- "Inú mi kìí dùn torí ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹ́rin ni ọjọ́ ìbí mi máa ń wáyé"
- Èmi àti Kolington kò fẹ́ra padà o, ọba Wákà kò fẹ́ ọba Fuji mọ́ - Salawa Abeni
- Kàyééfì ńla! Pẹ̀lúmi lu odindi ìlú kan ní jìbìtì ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó
- Ọ̀ọ̀ni kò láṣẹ láti yọ mí nípò, mi ò sì ní ááwọ̀ mọ́ pẹ́lú Aláàfin-Oluwo
- Nàíjíríà, ẹ fakọyọ lórí ìdènà Coronavirus àmọ ìròyìn òfegè léè ṣọṣẹ́ tẹ̀ bá ṣọ́ra - WHO
"Eyi lo jẹ ki Naijiria wa lara awọn orilẹede to n sọ ede Gẹẹsi lagbaye, eyi ko si tumọ si pe ileesẹ to n se iwe atumọ ede Gẹẹsi fontẹ lu awọn oyinbo Naijiria ọhun pe wọn pegede, a kan n fi igbesẹ naa mọriri aayan awọn onisẹ iwadi lori ede Gẹẹsi latẹyinwa ni."