You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus in Nigeria: Àjọ ètò ìlera lágbayé, WHO kan sárá sí Nàìjíríà lórí aáyan ìdènà àrùn Corona
Ajọ eleto ilera lagbaye, WHO ti ni ayederu iroyin yoo ran arun coronavirus lọwọ lati tan kalẹ lorilẹede Naijiria, afi bi ijọba ba tete gbe igbesẹ to yẹ lati dẹkun oniruuru iroyin ofege to n jade lori arun ọhun lọwọlọwọ.
Amọṣa, ajọ WHO kan sara si orilẹede Naijiria fun awọn igbesẹ to ni o gbe lati dena aisan Coronavirus eleyi to ti rapala wọ orilẹede Naijiria bayii.
- Àfagbárawọ̀ ló jẹ́ fáwọn arìnrìnàjò láti wọ pápákọ̀ òfurufú Nàíjíríà torí Coronavirus! Àwòrán rèé
- Gbé èlé gun owó ọṣẹ ìfọwọ́, ìbòjú àti ìnujú torí Coronavirus tó wọlé, ko fi ẹ̀wọ̀n jura - Ìjọba àpapọ̀
- Nàíjíríà kò gba gbẹ̀rẹ́ lórí Coronavirus, wo itú tà ń pa láti dènà alárùn ní pápákọ̀ òfurufú wa
- Ọmọ Nàìjíríà di agbábọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ tó ní ààrùn Coronavirus
- Wọ́n ti sin òkú Kazeem Tiamiyu tí wọ́n sọ pé SARS pa ní Sagamu
Ninu ọrọ to ba BBC News sọ, adari ileeṣẹ ajọ WHO lorilẹede Naijiria, Dokita Peter Clement ṣalaye pe, ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu igbesẹ ati akitiyan awọn orilẹede miran nilẹ Afirika lori didena arun Coronavirus yii, oṣuba kare lo yẹ fun orilẹede Naijiria.
O ni gbogbo ilakaka ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria, NCDC lati kapa arun coronavirus lawọn rii gẹgẹ bi eyi to lamilaaka ju awọn akẹgbẹ wọn gbogbo lawọn orilẹede miran nilẹ Afirika.
Amọṣa, o kọminu lori awọn aṣiwi, aṣigbọ ati aṣisọ iroyin nipa ayederu iroyin to n kaakiri nipa arun naa lorilẹede Naijiria. O ni o yẹ ki ijọba o ni ọpọlọpọ ijiroro ati ipolongo pẹlu awọn ileto fun araalu lati mọ bi wọn ṣe lee daabo bo ara wọn lọwọ itankalẹ arun naa.
Bakan naa ni ajọ eto ilera lagbaye, WHO tun ṣekilọ pe o yẹ ki ijọba ke sawọn ẹka eleto ilera aladani lati ṣugba wọn ninu ilakaka ati wawọ arun naa bọlẹ ko to ṣọṣẹ.
O ni bi ọrọ ṣe n lọ pẹlu bi ọrọ ṣe n lọ yii afaimọ o ki arun naa o ma tan kalẹ nipasẹ awọn oṣiṣẹ aladani lẹka eto ilera nitori aini imọ to to nipa rẹ.
Gbé èlé gun owó ọṣẹ ìfọwọ́, ìbòjú àti ìnujú torí Coronavirus tó wọlé, ko fi ẹ̀wọ̀n jura - Ìjọba àpapọ̀
Wayi o, ijọba apapọ Naijiria ti n fi ewe ọmọ mọ awọn ontaja ati alagbata ọja leti pe, wọn ko gbọdọ tori arun Coronavirus to wọle tọ wa ni Naijiria, maa gbe ele gun owo awọn ọja kan.
Ajọ to n daabo bo awọn ontaja lorilẹede Naijiria FCCPC, ninu atẹjade kan to fisita loju opo Twitter rẹ lo ti gbe ikilọ naa jade pẹlu afikun pe, iwa fifi owo le owo ọja laibikita tako ofin ihuwasi nilẹ wa.
Ajọ naa ni oun ti sakiyesi pe nikete tijọba kede pe wọn ti kofiri arun Coronavirus ni Naijiria, lawọn ontaja kan ti ro pe akoko ati ri taje se lo de fun awọn, ti wọn si n gbe owo gun awọn eroja to ni nkan se pẹlu ilera.
Lara awọn eroja to mẹnuba ni asọ ibọwọ, asọ iboju ati awọn eroja mii to ni nkan se pẹlu imọtoto ara bii ọsẹ ifọwọ lati dena arun, inuju ati bẹẹ bẹẹ lọ, tori pe awọn eroja yii wulo fun idena itankalẹ arun Coronavirus.
Ajọ FCCPC tun ni ọrọ ele owo ọja ọhun ko yọ awọn ileesẹ apoogun nlanla silẹ ati awọn ibudo itaja kan, ti wọn n yan ọmọ Naijiria jẹ eyi to ko jẹ kawọn eroja ọhun de arọwọto wọn.
O fikun pe bi awọn eroja ti araalu nilo lati dena itankalẹ arun Coronavirus ba ti wọ̀n ju, ti ko si si ni arọ̀wọ̀to wọ̀n, eyi lee mu ki ọwọja arun naa pọ̀ si ni Naijiria.
Atẹjade naa wa n kesi awọn ontaja atawọn ileesẹ apoogun pe ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ ninu wọn pe o n gbe ele gun owo awọn eroja wọnyi yoo finmu kata ofin, eyi to lee la ẹwọn lọ.
Ìjọba Ogun ti iléeṣẹ́ kan pa, èèyàn 28 wà ní ìyàsọ́tọ̀ torí Coronavirus
Saaju la ti kọ sọ fun yin pe eniyan mejidinlọgbọn to ni ibaṣepọ pẹlu ọmọ Italy to ko aarun Coronavirus wọ ipinlẹ Eko, ti wa ni ibudo iyasọtọ bayii.
Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Ogun fi sita loju opo ayelujara Twitter rẹ lọjọ Ẹti.
Ijọba ipinlẹ Ogun sọ pe, ọkunrin naa to n ṣiṣẹ l'orilẹ-ede Naijiria wa si ipinlẹ naa lẹyin to gunlẹ si papakọ ofurufu ilu Eko lati Milan, to si lọ si ileeṣẹ kan ni Ewekoro nipinlẹ Ogun.
Bakan ni ijọba Ogun ninu atẹjade naa sọ pe, ẹnu ko ya oun lati gbọ pe ọkunrin naa wa si ipinlẹ naa nitori pe pupọ ninu awọn to maa n gunlẹ si Eko, lo maa n wa si ọkan tabi omiran lara awọn ileeṣẹ to wa nipinlẹ Ogun.
Ṣugbọn ṣaa, gomina ipinlẹ naa, Dapo Abiodun sọ pe omi'nu nkọ ijọba nitori iye akoko ti yoo gba ki wọn o to le mọ esi ayẹwo awọn eniyan naa, ti wọn n reti lati ibudo ayẹwo nipinlẹ Eko.
Ati wi pe awọn ti awọn ti n ṣakitiyan lati tun ibudo iyasọtọ to wa ni ileewosan ikọṣẹ iṣegun oyinbo ni fasiti Olabisi Onabanjo, ati ilu Sagamu ṣe.
Gomina tun sọ pe, iroyin tẹ oun lọwọ pe ileeṣẹ ti ọkunrin naa lọ ti wa ni titi pa, ti ileeṣẹ naa si tun ti ni ibudo iyasọtọ to fi awọn eniyan mejidinlọgbọn naa si.