Salawa Abeni: Ìpolówó ọjà ni àwòrán tí èmi àti Ayinla Kolington ti dì mọ́ra, ìfẹ́ kọ́

Kii ṣe pe emi ati Alhaji Kollinghton Ayinla ti pada di tọkọtaya o! Eyi ariwo ti Ọbabirin orin Waka, Salawa Abẹni fi bọnu.

Laipẹ yii ni aworan kan jade kaakiri ninu, eyi ti Kolinghton Ayinla ati Salawa Abẹni ti di mọ ara wọn pẹki-pẹki.

Kini o sokunfa idahun Alhaja Salawa yii?

Ibeere ti o gba ori ayelujara yii ni Abeni Waka Queen ti dahun si bayii.

Eleyi si ti n mu ki ọgọọrọ awọn eeyan maa beere pe, abi Ọba Waka ti pada sile Ọba Fuji bayii ni?

Tọkọ tiyawo ni Alaaji Kolington Ayinla ati Salawatu Abẹni tẹlẹ, ki tirela to gba aarin wọn kọja lọpọ ọdun sẹyin.

Amọṣa, ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle kan, Alhaja Salawatu Abẹni ṣalaye pe, ko si ohunkohun to jọ fifẹra laarin oun ati Kebe-n-kwara o, ipolowo ọja lasan ni.

"Ipolowo ọja lasan ni. Emi o raye awọn nnkan bẹyẹn."

Kini Iya Okiki tun se lalaye?

Bakan naa ni Salawatu Abẹni wa gba awọn olorin ode oni niyanju, lati maa kọ ọrin to ni itumọ seti araye.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ni igba ti awọn to ṣaaju n kọ orin tiwọn, gbogbo ohun to n lọ lawujọ ni wọn fi n kọrin lati ṣi araalu leti.

Bẹẹ lo tun rọ wọn lati maa tẹriba fun agba.