Salawa Abẹni: ₦50 péré làwọn èèyàn fí ń pè mí fún ayẹyẹ nígbà tí mó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja olorin Waka, Alhaja Salawa Abẹni sọ pe, oun ko lọwọ si awuyewuye ta lo da Fuji silẹ tawọn olorin kan n gba bi ẹni n gba igba ọti.

Queen Salawa to sọrọ naa ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba lọjọ Ẹti ṣalaye pe, to ba tiẹ jẹ pe oloogbe Alhaji Sikiru Ayinde Barrister gan an lo da Fuji silẹ, o yẹ kawọn eeyan fi Barrister silẹ lati sun nibi to wa.

O wa ke si gbogbo olorin Fuji lati fọwọ ṣo ọwọ pọ lati gbe orin Fuji larugẹ, ki wọn si gbagbe ariyanjiyan lori ẹni to da Fuji silẹ.

Alhaja Abẹni fikun ọrọ rẹ pe lootọọ l'oun n kọ orin Waka, ṣugbọn oun kọ l'oun da orin Waka silẹ.

Bakan naa, Salawa tun ṣalaye ọrọ lori ibaṣepọ rẹ pẹlu Alhaji Kollington Ayinla, o ni baba ọmọ oun ni Kollington jẹ, amọ oun ko tii pada sile rẹ titi di asiko yii.

Ṣugbọn o sọ pe ọja t'ọmọ ba ti wọ, o ti dokuta.

Bi ifọrọwerọ BBC Yoruba naa se lọ ree pẹlu Salawa Abẹni

Salawa Abẹni sọ pe, ọmọ ọdun mẹtala wa, ti oun fi gbe awo orin waka akọkọ jade lọdun 1976, o ni iranti aarẹ ologun orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, ologbe Ọgagun Murtala Muhammed ni awo orin naa da le lori.

Queen Salawa, to ni iwe mẹfa l'oun ka tun sọ pe, aadọta kọbọ lawọn eeyan maa fi n pe oun sode nigba t'oun bẹrẹ iṣẹ orin kikọ.

O ni baba oun ko nifẹ si iṣẹ orin kikọ, ṣugbọn mama oun nifẹ ṣii, amọ ọrẹ baba oun lo ba baba oun sọrọ, ko to gba.

Salawa tun ṣalaye pe aarẹ ara lo ṣe oun, kii ṣe ti aarun gogongo gẹgẹ bi ọpọ ti n ṣọ kaakiri.

Salawa ni ''ọjọ ti inu mi dun ju laye lọjọ ti mo gbe awo akọkọ mi jade, bẹẹ ni ọjọ ti inu mi bajẹ ju ni ọjọ ti mo padanu ọmọkunrin mi.''

Queen Salawa Abẹni sọ pe ''ẹbun lorin kikọ fun emi, Ọlọrun lo fun mi. Ko si ibi ti imisi orin ko ti le wa fun mi. Mo le ri nnkan loju, ki n si sọ dorin.''