You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bamise Ayanwola BRT: Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Eko sọ pé irọ́ ni pé wọ́n gé ẹya ara ọmọbìnrin nàá
Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Abiodun Alabi, ti kede pe ko si ẹya ara to di awati lara Bamise Ayanwola, ọmọbinrin to di awati ninu ọkọ BRT.
Nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun ni Ọgbẹni Alabi ti sọ pe, oun ṣabẹwo si mọṣuari ti oku ọmọbinrin naa wa, ti oun ko si ṣakiyesi ẹya ara rẹ kankan ti wọn ge.
Ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2022, ni Bamisẹ di awati lẹyin to wọ ọkọ akero ijọba ipinlẹ Eko, BRT, lati agbegbe Chevron ni Lekki, to si n lọ si Oshodi.
Ọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ni wọn ri oku rẹ.
Bawo ni Bamise Ayanwola ṣe rin arinfẹsẹsi?
Awọn olugbe agbegbe Ogogoro ni Lagos Island lo ti kọkọ ri oku rẹ lori afara Carter ni ọsẹ to kọja, ti wọn si fi to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti.
- Wọ́n gbé ìbọn sí mi léti lásìkò tí mò ń wa ọkọ̀ BRT tí Bamise ti dàwátì, mi ò mọ bó ṣe ń ṣe mí rárá- Dẹ́rẹ́bà BRT
- Ẹ má bẹrù láti wọ ọkọ̀ BRT wa, kò séwu - Gómìnà Sanwo-Olu
- Timothy Adegoke: Raheem Adedoyin ní káwọn òṣìṣẹ́ Hòtẹ́ẹ̀lì òun fi Bíbélì búra pé wọ́n ò ní tú àṣírí
- Wo ohun tí Sunday Igboho ṣe ní kété tó jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Cotounou
Ohun ti a gbọ ni pe agbegbe Chevron Estate ni Ajah ni oloogbe naa ti n ṣiṣẹ gẹgẹbi aranṣọ, ti o si maa n lọ si Ọta nipinlẹ Ogun lọdọ ẹgbọn rẹ obinrin lati lọ ṣe isinmi opin ọsẹ lọsọọsẹ.
Omidan Ayanwọle n lọ si Ọta lọjọ Satide lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keji, lẹyin to pari iṣẹ tan ni Ajah ,lo fi gun bọọsi BRT naa ni nkan bi aago meje alẹ.
Oshodi ni bọọsi BRT naa n lọ ṣugbọn omidan naa ko de oshodi, oku rẹ ni wọn ri.
Ọrọ Kọmisanna ọlọpaa lori iku Bamise
Ṣaaju ni iroyin sọ pe awọn to pa ọmọbinrin naa gé oju ara rẹ lọ.
Amọ ninu ọrọ rẹ, Kọmisanna ọlọpaa sọ pe oun ati awọn ẹbi oloogbe ni awọn jọ lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa ni Yaba, ti oun ko si ri ibi kankan ti wọn ge lara rẹ bi iroyin ṣe n sọ.
O ni ṣugbọn, ayẹwo oku yoo fihan boya wọn fi ipa ba a lopọ ṣaaju iku rẹ.
Ẹni ọdun mejilelogun ni Bamise.
Kọmisanna sọ pe ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ DSS lo tẹ awakọ BRT naa, Andrew Nice Ominikoron, to jẹ afurasi akọkọ lori iku Bamise, ni ipinlẹ Ogun nibi to sapamọ si.
Afurasi naa sọ fun awọn ọlọpaa pe awọn ọkunrin kan ti oun gbe pẹlu Bamise lo ṣeku pa a.
O ni niṣe ni wọn yọ ibọn si oun, ti ẹru si ba oun debi pe gbogbo nkan ti wọn ba ni ki oun ṣe ni oun ṣe.
Ọgbẹni Ominikoron ṣalaye pe bi ọmọbinrin naa ṣe ṣunkun to nigba ti wọn n wọ bọ silẹ lati inu ọkọ, oun ko ni agbara lati soola rẹ.