Hero Tortoise: Ìjàpá 14 ni wọn yà sọ́tọ̀ láti bí Ìrère 2000, kí ìran wọn má baà parun

Iran awọn ijapa ti n lọ lorilẹ aye amọ ọna ti iran ijapa ko fi ni parun lo mu ki wọn ya ijapa mẹrinla sọtọ, ni Santa Cruz to wa lagbegbe Galapagos Isle, lorilẹede Espannola.

Ni aadọta ọdun sẹyin, ijapa meji pere lo wa lorilẹede naa, eyi to mu ki wọn gunle akanse eto ọsin ijapa, ki iran ijapa maa baa parun lorilẹ aye.

Awọn ijapa naa si lo bi ọmọ to ti le ni ẹgbẹrun meji bayii sugbọn ogbologbo ijapa kan wa ninu wọn, to ti le ni ọgọrun ọdun, to si bi ọmọ to le ni ẹgbẹrin.

Iroyin naa ni Diego lorukọ ijapa ọlọmọ pupọ naa, to si ti fẹyinti lẹyin isẹ asekara lati daabo bo iran rẹ ko maa baa parun.