Àwọn bísọ̀ọ̀bù Aguda rọ ààrẹ Buhari lati kọ̀wé fipò sílẹ̀

Ẹgbẹ́ àwọn Bísọ̀ọ̀bù ìjọ páàdì Catholic Bishop conference of Nigeria (CBCN) tí ke pe ààrẹ Muhammadu Buhari láti kọ̀wé fipò sílẹ̀ tí kò bá le fòpin sí ìpànìyan tó ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Àwọn bísọ̀ọ̀bù sọ̀rọ̀ ọ̀hún lásìkò tí wọn ń sọ̀rọ̀ lórí ìpànìyan tó ń wáyé jákèjádò ilẹ̀ yìí pàápàá jùlọ èyí tó wáyé láìpẹ̀ yìí tí o sì gba ẹmí ènìyan tó tó ọgọ́rùn ní ìpínlẹ̀ Plateau.

Wọn sọ̀rọ̀ náà nínú àtẹ̀jáde kan ti Augustine Akubeze tó je ààrẹ CBCN fi síta, ti wọn bu ẹnu àtẹ́ lu ìtàjẹ̀ sílẹ̀ tó ń wáye.

"òòsà bóò le gbè mi fimi sí bóo se bámi, bí ààrẹ o bá le wá ojúùtú sí ìpànìyàn láti ọwọ́ àwọn darandaran tí wọn ń fẹ̀mi àwọn eniyan sòfò láì rí ìdíwọ kankan''

"Bí ààrẹ ò bá le dáàbò ẹmi àwọn ará ìlú, ó túmọ̀ sí pe kò yẹ lẹ́ni to yẹ ko máa darí orílẹ̀-èdè"

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ akọwé ẹgbẹ ọhún Fada Evaristus Bassey tó bá BBC sọ̀rọ̀ sàlàyé pé ojúṣe ìjọba ní lati sààbò bo ará ìlú bótilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ń gbìyàjú síbẹ̀, kò sí ojúùtú sí ìsòrò.

Akọwé ọ̀hún ní kìí ṣe pé àwọn sọ pe kí ààrẹ fi ipò sílẹ̀ súgbọn àwọn fẹ ki ó fi ara rẹ han gẹ́gẹ́ bíì olórukọ rere tí gbogbo eniyan mọ̀ọ́ sí.

Ó fi kún pe ìjọbá ní láti sàtúntò àwọn eléto ààbò nítori iṣẹ́ wọn kò tó.