Kókó òkò ọ̀rọ̀ tí Pásítọ̀ Tunde Bakare sọ ranṣẹ́ sí Tinubu

Tunde Bakare ati Aarẹ Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Pasitọ agba ijọ Citadel Global Community Church, Tunde Bakare, ti ṣapejuwe awọn ilana iṣejọba ijọba apapọ ti iṣejọba Tinubu n gbe kalẹ gẹgẹ bi eyi to tako ifẹ ati igbayegbadun araalu. Bakare sọ ọrọ naa lasiko iwaasu kan to ṣe ni ọjọ Aiku nile ijọsin rẹ to wa niluu Eko.

Pasitọ naa ti oun funra rẹ fi igba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC, ati oludije sipo aarẹ, ni igbesẹ Aarẹ Bola Tinubu lati igba to ti de ipo jẹ ailarojinlẹ, to si ti ba ọr ọ aje jẹ si. Awọn ilana naa lo sọ pe o ti sọ ọpọlọpọ idile sinu aini, ti awọn oniṣowo ati ileeṣẹ kan si ti n ko gba wọle.

Awọn koko mii ti Bakare mẹnuba

Pipin nnkan fun araalu ko le yanju orisun iṣoro

Pasitọ Bakare sọ pe botilẹ jẹ pe aarẹ kede pipin awọn nnkan amayedẹrun, o ni awọn nnkan naa ko le yanku orisun ibi ti wahala ti wa. "Nitori naa la ṣe n fẹ ki o mojuto ibi ti isoro yii ti bẹrẹ gan-an. " Gbe ajaga kuro ni ọrun awọn mẹkunnu, lepa awọn to ji ogun araalu, gba a pada lọwọ wọn, ko si lo o fun anfaani awọn ọmọ Naijiria. " Bakare ni nnkan ti oun n sọ ni pato ni pe iwa ibajẹ ni ki aarẹ pa, kii ṣe awọn ọmọ Naijiria.

Emefiele ko gbọdọ jẹ ẹran irubọ

Lara nnkan ti Pasitọ Tunde Bakare tun sọrọ le lori ni bi ijọba ṣe mu gomina banki CBN si ahamọ. Bakare sọ pe lootọ lo ṣe e ṣe ki Emefiele ṣe awọn aṣise nipa awọn ilana to ṣe lori ọrọ owo Naijiria, o ni ṣugbọn ijọba apapọ ko gbọdọ fi ṣe ẹran irubọ. Nitori awọn akọsilẹ ofin CBN 2007, o ṣeeṣe pe gomina CBN ko gbe igbesẹ kankan lai ṣe pe aarẹ buwọlu u. Tunde Bakare ni oun faramọ fifi oju Emefiele wina ofin, to ba jẹbi ẹsun kankan, "ṣugbọn igbesẹ ijọba jọ gbigba ẹsan oselu lara Emefiele, nitori awọn iṣẹlẹ to waye ṣaaju idibo aarẹ ọdun 2023."

Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Bakare ni ara ailarojinlẹ lo mu ki Aarẹ Tinubu dari ajọ Ecowas, lati kede pe oun yoo kogun ja Niger. O ni bi aarẹ ṣe kọkọ kede lilo ọmọ ogun lodi si awọn ọmọ ogun to ditẹgbajọba ni Niger" ti fi Naijiria ati gbogbo ẹkun Iwọ-oorun Africa sinu wahala nla. "Dandan ni atilẹyin araalu, ki kiko ogun ja orile-ede mii to le yọri si rere."