Ìyàwó gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Lekan Olatunji jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Lekan Olatunji/Instagram
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Lekan Olatunji lo wà nínú ìbànújẹ́ báyìí bí ó ṣe pàdánù rẹ̀, Ifedolapo Olatunji.
Olatunji tó kéde ikú ìyàwò náà rẹ̀ lójú òpó Instagram rẹ̀ ní Ọba kí kò ṣe é bi lẹ́jọ́ ni Ọlọ́run tí ènìyàn sì gbọ́dọ̀ gba nǹkan tí ó bà dà sí ènìyàn ní agbada.
Ó ní láti ọdún mẹ́rìndínlógún tí àwọn ti fẹ ara àwọn ni ìyàwó òun ti gba òun bí òun ṣe rí, tó sì mú òun sún mọ́ Ọlọ́run.
Ó ní ìbànújẹ́ ọkàn ló jẹ́ fún òun pé pẹ̀lú bí àwọn ṣe ná ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lórí ìlera ìyàwó òun náà, o dún òun pé àwọn padà pàdánù rẹ̀ sọ́wọ́ ikú.
Ohun tó ṣokùnfà àìlera ìyàwó òṣèré náà ni wọn kò fi léde.
Nínú oṣù Kẹfà ọdún 2022 ni òṣèré náà fúnra rẹ̀ ní ìjàmbá ọkọ̀ lásìkò tó ń lọ kópa níbi eré kan ní Ikorodu.
Ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré ló ti ń fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí Olatunji lórí ẹ̀rọ ayélujára rẹ̀.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post

Oríṣun àwòrán, Lekan Olatunji/Instagram








