Iléẹjọ́ gba béèlì Emefiele, wọ́n ní kó kúrò ní àhámọ́ DSS

Oríṣun àwòrán, Others
Adajọ agba ni ilẹjọ giga nipinlẹ Eko, Nicholas Oweibo ti gba beeli gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ, Godwin Emefiele.
Emefiele lo ti wa ni ahamọ DSS fun igba diẹ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Adajọ naa paṣẹ fun adari ajọ DSS ni Naijiria, Yusuf Bichi lati kuro ni ahamọ DSS lọ si ọgba ẹwọn nibi ti yoo wa.
Eyi ko ṣẹyin ipẹjọ ti agbẹjọrọ Emefiele pe tako bi o se wa ni ahamọ DSS fun igba pipẹ.
Oṣẹ to kọja ni DSS gbe Emefiele lọ si ileẹjọ lori ẹsun meji to niise pẹlu ni ni ohun ija bii ibọn lọwọ.
Ajọ DSS ni Emefiele ni ibọn lọwọ lai si pe o ni aṣẹ lati gbe iru ohun ija bẹẹ lọwọ.
Amọ Emefiele ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ti adajọ si gba beeli rẹ pẹlu ogun miliọnu naira pẹlu oniduro kan.
Adajọ gba oniduro rẹ pẹlu iwe irinna meji pẹlu ileẹjọ pẹlu ami idanimọ pe tirẹ ni.
Bakan naa ni adajọ ni ki wọn fi Emefiele si ọgba ẹwọn Ikoyi titi ti wọn yoo fi mu gbogbo ohun to rọ mọ gbigba beeli rẹ.
Ìwà tí ìjọba n hù sí ẹ̀gbọ́n mi kò dárá, lẹ́yìn tó sin Naijiria fún ọdún mẹ́sàn-án- George Emefiele
Saaju ni ẹnikan to jẹ aburo fun gomina banki apapọ Naijiria (CBN), George Emefiele, ti sọ pe iwa ti awọn alaṣẹ n hu si Godwin Emefiele ko bojumu rara.
Bakan naa lo sọ pe ija to waye laarin awọn oṣiṣẹ DSS ati ti ọgba ẹwọn lẹyin ti adajọ gba beeli Emefiele pẹlu ogún miliọnu Naira, ko tọna labẹ ijọba awaarawa.
Arakunrin George Emefiele sọ pe ọwọ ti ijọba fi mu ẹgbọn oun ko dara, lẹyin to ti sin Naijiria fun ọdun mẹsan-an.
O ni ẹgbọn oun kii ṣe ẹni to le salọ.
“Ọdun mẹsan-an gbako lo fi ṣiṣẹ sin Naijiria. Amọ ṣe bi ijọba ṣe fẹ ẹ san ẹ̀san fun un re e?”
O ni eyi ko tọna, o si kesi ijọba apapọ lati gbọnran si aṣẹ ile ẹjọ nitori pe ẹgbọn oun ko tọ si awọn nnkan to n koju lọwọlọwọ lẹyin to fi ara rẹ sin orilẹ-ede.
Ọgbẹni Emefiele sọ pe nnkan ti awọn n fẹ ni pe ki ijọba tẹle ilana to yẹ lori ọrọ rẹ.















