‘’Ìdí nìyíí tí a fi sún ètò ìkànìyàn oͅdun 2023 sí iwájú’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijoͅba aareͅ Buhari ti salaye idi ti woͅn fi sun eto ikaniyan to yeͅ ko waye ni Osu Karun un si iwaju.

Eyi n waye leͅyin ti aareͅ Buhari buwoͅlu ki woͅn sun eto ikaniyan cencus naa si iwaju.

Oͅjoͅ Keͅta, Osu Karun un si Oͅjoͅ Keje, Osu Karun un, oͅdun 2023 ni o yeͅ ki eto ikaniyan naa waye.

Amo ninu ateͅjade ti minisita fun eto iroyin ati asa, Lai Mohammed fi lede lo ti kede pe aareͅ Buhari ti buwolu isusiwaju eto ikaniyan naa.

Idi ni yii ti a fi sun eto ikaniyan naa

Ki ijoͅba to kede isunsiwaju naa ni adari Ajoͅ National Population Commission, NPC, Inuwa Jalingo ti soͅ pe o seese ki awoͅn sun eto naa siwaju.

Jalingo Inuwa ni eto to yeͅ ko koͅkoͅ waye sͅaaju kika eniyan to pe ni Building Numbering ko I tii waye.

O ni awoͅn ni ipenija peͅlu awoͅn eͅroͅ woͅn, nitori naa ni awoͅn se gboͅdoͅ se awoͅn eto naa ki awoͅn to lee se eto ikaniyan.

Adari ajoͅ NPC naa ni awoͅn feͅ koͅkoͅ ka awoͅn ile igbe to wani Naijiria, to si ni awoͅn kan ti bajeͅ amoͅ woͅn nilo lati tun un se ki woͅn le ka awoͅn

Buhari buwọ́lu sísún ètò ìkànìyàn síwájú

Aare Buhari

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu sísún ètò ìkànìyàn tí wọ́n tí kọ́kọ́ ní yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kẹta oṣù karùn-ún ọdún yìí síwájú.

Buhari ní kí ìjọba tuntun tí yóò gbà ipò lọ́wọ́ òun ni ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Karùn-ún mú ọjọ́ àti àsìkò mìíràn tí ètò náà yóò wáyé tí wọ́n bá ti gorí ipò tán.

Nígbà tí Ààrẹ Buhari ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ kan àti alága àjọ tó ń rí sí ìyè ènìyàn tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí, Nasir Isa-Kwarra ní ìlú Abuja lọ́jọ́ Ẹtì.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Mínísítà fétò ìròyìn àti àṣà Nàìjíríà, Lai Mohammed fi léde lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé ó pọn dandan pé kí ètò ìkànìyàn wáyé lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógún tí ètò náà wáyé kẹ́yìn.

Ó ní ètò náà yóò fún ìjọba ní àǹfàní láti mọ iye nǹkan tó wà ní orílẹ̀ èdè yìí lójú à àti lè pèsè àwọn ohun amáyédẹrùn fún tẹrú tọmọ.

Ààrẹ ní ìgbáradì ti ń lọ gidigidi láti ṣètò ìkànìyàn tó gbé oúnjẹ fẹ́gbẹ́ gba àwo bọ̀, tó sì kan sáárá àjọ NPC fún àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ ṣàmúlò láti fi kànìyàn tó péye.

Bákan náà ló wòye pé ètò EAD tó ti ṣáájú wáyé ti ṣàfihàn pé àjọ náà ti ṣetán láti ṣètò ìkànìyàn tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìkànìyàn ní àgbáyé.