Ọdún ọmọ ìlú Ìbarà bẹ̀rẹ̀ l’Abẹ́òkúta lákọ̀tun

Oríṣun àwòrán, Awọn ọmọ Ibara/Others
Inu idunnu ati ayọ nla ni gbogbo awọn ọmọ ilu Ibara to wa ni Abẹokuta, olu-ilu ipinlẹ Ogun kaakiri agbaye bayii wa, pẹlu bi ọdun wọn ti wọn pe ni Ọdun Ọmọ Ibara ṣe bẹrẹ lakọtun.
Ọdun yii ni awọn ilu Ibara maa n ṣe lati fi bọ awọn oriṣa wọn, ati lati fi gbe awọn aṣa ibilẹ abalaye wọn larugẹ kaakiri agbaye.
Ẹẹkan ṣoṣo ni ayẹyẹ Ọdun Ẹ̀fẹ̀ Ibara maa n waye laarin ọdun mẹta, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Oni, Ọjọru tii ṣe ọjọ kẹtadinlogun ni eto ọhun bẹrẹ pẹlu bibọ Yemọja ni abule Arò ati ninu odo Ọgun, ti yoo si pari lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun ti a wa yii.
Lara awọn alakoso eto naa, Oloye Ọkanlawọn Oyewọle to ba BBC YORUBA sọrọ jẹ ko di mimọ pe ọna ara ọtọ ni eto ayẹyẹ ọdun yii yoo fi waye, nitori awọn ilana ti wọn ti la kalẹ.
Oloye Oyewọle sọ pe lọdọọdun lawọn maa n ṣafihan awọn ohun to wa ninu oriki wọn, eyi ti wọn fi n pe wọn ni ‘Ọmọ oni Gẹlẹdẹ ile Ibara’
“Ọdun Yemọja la maa n kọkọ ṣe, ati pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin ni yoo bẹrẹ, nitori pe Yemọja lo fun Ẹfẹ ati Gẹlẹdẹ ni ọmọ.
Ẹfẹ lo maa n kọrin yin awon to ba se dáadáa, tí yóò si bu awọn to ba n huwa ibajẹ lawujọ.

Oríṣun àwòrán, Ọkanlawon Oyewọle
Oloye Ọkanlawọn tẹsiwaju pe; “Gbagede inu ọja Omida ni a ti maa ṣe Ẹfẹ naa ni alẹ Ogunjọ mọjumọ ọjọ kọkanlelogun. Awọn eeyan kan n gbọ nipa Ẹfẹ ni, wọn ko mọ itunmọ rẹ, Ẹfẹ yatọ si awada bi awọn kan ṣe maa n lero.
“Gbogbo ọmọ ilu Ibara kaakiri agbaye ni wọn maa wa sile lati wa kopa ninu ọdun Ẹ̀fẹ̀ yii, nitori pe bi a ṣe maa n ṣe lọdun mẹta-mẹta niyẹn.

Oríṣun àwòrán, Ọkanlawon Oyewọle
Oloye naa tun salaye siwaju pe: “Awa Ibara jẹ pataki ni ilu Abeokuta lati bọ odo Ogun.
Awọn abọgun lo maa lọ sinu odo Ogun lati bọ Yemọja, iyẹn lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin, ti a si maa gbadura.
“Gẹlẹdẹ la maa ṣe gbẹyin, gbogbo idile to ni Gẹlẹdẹ ni wọn maa gbe e jade lati ọjọ kọkanlelogun titi di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹrin ti ayẹyẹ naa yoo pari.”

Oríṣun àwòrán, Aworan awon oniṣẹṣe/Ọkanlawon Oyewọle
Bakan naa ni Oloye Oyewọle jẹ ko di mimọ pe ipa rere ni ayẹyẹ yii maa mu wọ ilu Ibara, paapaa ilu Abẹokuta bii idagbasoke eto ọrọ aje lẹyin ti wọn ba pari, ti o si ni ti ọdun yii yoo tun larinrin ju ti tẹlẹ lọ.















