Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn yá, mi ò gba ìdájọ́ 'Tribunal' wọlé - Adebutu

Oríṣun àwòrán, Others
Olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú People’s Democratic Party, (PDP) ní ìpínlẹ̀ Ogun, Ladi Adebutu ti ní òun kò gba ìdájọ́ tí ìgbìmọ̀ gbé awuyewuye ìbò ní ìpínlẹ̀ náà gbé kalẹ̀ lórí ètò ìdìbò àwọn.
Adebutu ní ìdájọ́ náà banilọ́kàn jẹ́ púpọ̀, tó sì jẹ́ ìdúnkokò ńlá sí ètò ìṣèjọba àwaarawa.
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọgbọ́n ọjọ́ oṣù Kẹsàn-án ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà da ẹjọ́ tí Adebutu pè tako gómìnà Dapo Abiodun nù pé ẹja náà kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.
Ètò ìdájọ́ náà ló wáyé fún wákàtí mọ́kànlá.
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC kéde Dapo Abiodun ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, (APC), gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ náà tó wáyé nínú oṣù Kẹta ọdún 2023 pẹ̀lú ìbò 276,298.
Adebutu ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ló tẹ̀lé nígbà tí òun rí ìbò 262,383, TÍ Biyi Otegbeye tẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress wà ní ìpò kẹta pẹ̀lú ìbò 94,754.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti Adebutu nígbà náà ní àwọn kò gba èsì ìbò tí INEC kéde náà wọlé tí wọ́n sì wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Abiodun lọ síwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ awuyewuye èsì ìbò.
Wọ́n fẹ̀sùn kàn pé Abiodun kọ́ ló ní ìbò tó pọ̀ jùlọ àti pé INEC kò tẹ̀lé òfin ètò ìdìbò lásìkò ìbò náà.
Bákan náà ni wọ́n tún fẹ̀sùn kàn pé àwọn jàǹdùkú da ètò ìdìbò rú ní àwọn ibùdó ìdìbò tó lé ní 99 tí èyí sì dí àwọn ènìyàn tó lè ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì lọ́wọ́ láti kópa níbi ìdìbò náà.
Ki lawọn ẹbẹ ti Ladi Adebutu gbe ka iwaju ile ẹjọ idibo gomina ni Ogun?
Ladi Adebutu ní kí ilé ẹjọ́ kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò gómìnà tó wáyé ní ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹta, kí wọ́n gba ipò náà lọ́wọ́ Dapo Abiodun.
Ó ní kí ilé pàṣẹ kí ètò ìdìbò tuntun mìíràn wáyé ní àwọn ibùdó ìdìbò 99 ní wọ́ọ̀dù mọ́kànlélógójì káàkiri ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rìndínlógún tí ètò kò ti wáyé tẹ́lẹ̀ àtàwọn ibi tí wọ́n ti da ètò ìdìbò rú.
Àmọ́ àwọn adájọ́ tí wọ́n ń gbọ́ awuyewuye náà ní Adebutu kò fi ẹ̀rí gbe àwọn ẹ̀sùn rẹ̀ lẹ́sẹ̀ pé àwọn kan dí àwọn ènìyàn láti dìbò lásìkò ìbò náà gbe ẹ̀sùn rẹ̀ lẹ́sẹ̀.
Wọ́n ní kò sí ẹ̀rí pé ìwà màgòmágó wáyé níbi ètò ìdìbò náà tàbí pé iye ìbò tí wọ́n dì pọ̀ ju àwọn tó yẹ kó dìbò lọ tàbí pé Abiodun kò yẹ láti díje dupò náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sùn tí Adebutu fi kàn.
Wọ́n ní nítorí náà ni àwọn ṣe dá ẹjọ́ náà nù pé kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá.

Oríṣun àwòrán, Others
Nígbà tó ń fèsì sí ìdájọ́ náà, Adebutu ní àwọn adájọ́ náà kò ṣe àwọn àgbéyẹ̀wó àwọn ẹ̀rí tí àwọn kó sí iwájú ilé ẹjọ́.
Agbẹnusọ Adebutu, Afolabi Orekoya ní ó ti darí àwọn ikọ agbẹjọ́rò rẹ̀ láti gba ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lọ nítorí àwọn kò ní sinmi àyàfi tí àwọn bá rí ìdájọ́ òdodo gbà.
Ó ní àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ètò ìṣèjọba àwaarawa àti òfin àti pé èyí ló mú àwọn gbé ìgbésẹ̀ òfin láti gba ẹ̀tọ́ àwọn padà.
Ó fi kun pé òun ní ìfarajìn láti ri dájú pé ìfẹ́ àwọn ènìyàn wá sí ìmúṣe lórí ètò ìdìbò náà.
Ó ṣàlàyé pé àwọn ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ ni àwọn kó síwájú ìgbìms tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà, tí àwọn sì ní ìgbàgbọ́ pé tí àwọn bá dé ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn, àwọn máa rí ìdájọ́ tó tẹ́ àwọn lọ́rùn gbà.
Bákan náà ló ní ó jẹ́ ohun tó kọnilóminú pé ilé ẹjọ́ kìí ṣe ibi tí ènìyàn ti le rí ìdájọ́ òdodo gbà mọ́ lásìkò yìí.
Ó wá fi dá àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ lójú pé òun kò ní jẹ́ kí ìdájọ́ náà kó àárẹ̀ ọkàn bá òun.
Lónìí ni ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí PDP pe Gómìnà Dapo Abiodun yóò dájọ́

Oríṣun àwòrán, Prince Dapo Abiodun/X
Oni ọjọ Abamẹta ni igbimọ adajọ kotẹmilọrun to n ri si ẹjọ ti oludije si ipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP, Ladi Adebutu pe gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun pe ko wọle ibo gomina ipinlẹ naa.
Lọjọ kẹrin oṣu Kẹsan an yii ni igbimọ igbẹjọ naa sun idajọ wọn si ọgbọnjọ oṣu Kẹsan an yii.
Hamidu Kunaza to jẹ adari awọn adajọ to n ṣe igbẹjọ naa ti sọ ṣaaju fun gbogbo awọn tọrọ kan pe ni ipari oṣu kẹsan an ni iadajọ yoo waye.
Akọwe igbimọ igbẹjọ kotẹmilọrun naa, Obioma Ezenta fi lede pe ọjọ Abamẹta yii ni idajọ naa yoo waye.
Bakan naa ni oludamọran oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP, Afolabi Orekoya sọ pe igbimọ igbẹjọ ọhun ti sọ fawọn nipa idajọ oni.
Ajọ eleto idibo INEC kede pe gomina Abiodun ri ibo 276,298 nigba ti Adebutu ṣe ipo keji pẹlu ibo 262,38 ninu ibo gomina to waye lọjọ kejidinlogun oṣu Kẹta.
Adebutu tako esi idibo yii, o si n sọ fun ileẹjọ lati kede oun gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo naa.















