Students Kidnap Coverage: Akòrọ̀yìn Nàìjíríà korò ojú sí ìròyìn òkèèrè lórí ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́bìnrin

Bata awọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wọn ji gbe

Awọn àgba bọ, wọn ni ọrọ okeere, ti ko ba le kan, a si din kan.

Ohun lo difa fun akọroyin ati onkọwe ọmọ Naijiria, Adaobi Tricia Nwaubani, to be ẹnu atẹ lu agbekalẹ iroyin awọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere, lori awọn iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọbinrin nile iwe wọn lorilẹ ede Naijiria.

O ni asọdun awọn ileeṣẹ iroyin pọ bẹrẹ lati iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọbinrin ile iwe Chibok lọdun 2014, to fi de bi iṣẹlẹ ile iwe Kankara ni Katsina.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni bi awọn akọroyin ti dẹnu bo ọrọ awọn akẹkọọbinrin to le lugba ti wọn jigbe ni Chibok nipinlẹ Bornu, ṣugbọn awọn nnkan to t'ẹyin rẹ jáde ko dara.

Ṣaaju iṣẹlẹ Chibok, ẹkọọkan lawọn ọmọ Naijiria maa n ri adarí Boko Haram, Abubakar Shekau yala lori ayelujara tabi ẹrọ amohunmaworan.

ilegbe awọn akẹkọọ

Shekau bẹrẹ si ni kọ awọn eeyan lominu lẹyin to dunkoko iku mọ aarẹ Naijiria nigba naa, Goodluck Jonathan, ati aarẹ Amẹrika igba naa, Barack Obama.

Ṣugbọn lẹyin iṣẹlẹ Chibok, awọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere bẹrẹ sí ni gbe ohun gbogbo ti Shekau ba ti sọ.

Shekau naa bẹrẹ si ni fun wọn ni oriṣiiriṣii fidio awọn akẹkọọbinrin ti wọn jigbe to si eleri lati ta wọn.

Awọn ti wọn jigbe ti ṣalaye pe niṣe lawọn ajinigbe maa n dunnu nigba kuu gba tawọn ileeṣẹ iroyin ba n sọ nípa ìṣẹlẹ náà.

Iṣẹlẹ Chibok lo sọ Shekau di ilumọọka lọdọ awọn akọroyin

Ọpọ iroyin tawọn kan n gbe kiri lori iṣẹlẹ Chibok gan an kii ṣe otitọ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere ri iṣẹlẹ ijinigbe ileewe Chibok bi ikọlu eto ẹkọ ọmọbinrin ni Naijiria, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ.

Lara awọn to jajabọ lọwọ awọn ajinigbe Boko Haram sọ pe ohun tawọn janduku to yabo ileewe awọn fẹ jale lasan an ni.

Awọn akẹkọọbinrin Chibok

Oríṣun àwòrán, AFP

Bi Boko Haram ṣe bẹrẹ si ni so ado oloro mọ awọn ọmọdebinrin lara lẹyin iṣẹlẹ Chibok fihan pe wọn ṣe bẹẹ k'awọn akọroyin tun le maa sọ nipa wọn ni.

Oríṣìíríṣìí ọmọ Naijiria lo ti bọwọ s'ọwọ awọn ajinigbe ti wọn si ti san owo lati gba ominira, amọ kii ṣe bi ti ọdunrun ùn awọn ọdunkunrin akẹkọọ ile iwe girama ilu Kankara ni Katsina nipari ọdun 2020.

Michell Obama

Oríṣun àwòrán, The office of the First Lady

Ijọba Naijiria ni awon janduku agbebọn lo yabo ile iwe naa

Ṣugbọn awọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere so iṣẹlẹ naa pọ mọ iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọbinrin Chibok to ti ṣẹlẹ bi ọdun mẹfa sẹyin.

Lakotan, onkọwe yii ni bi awọn ileeṣẹ iroyin ilẹ okeere yìí ti n ṣe agbekalẹ iroyin lori awọn janduku ajinigbe ati Boko Haram ṣe pataki.

Bakanna lo sọ pe ijọba gbọdọ wa nnkan ṣe sọ̀rọ̀ eto abo to mẹhẹ ni Naijiria ki wọn si ṣe iranti awọn ti wọn ti ṣeku pa.