Serena Williams: Wang tún da àlá Ife ẹ̀yẹ kẹrìnlélógùn fún Serena Williams rú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọrọ Serena Williams, agbabọọlu ẹlẹyin ori papa ati ilepa rẹ lati gba ife ẹyẹ idije lawn tennis Grandslam fun igba kẹrinlelogun tun ti dete.
Wang Qiang, ọmọ orilẹede China lo bomi pana ala yii lẹẹkan sii nibi idije Australian Open to n lọ lọwọ.
Serena Williams jẹ ọkan lara awọn odu elere idaraya Lawn Tennis ti itan agbaye ko lee gbagbe laye lẹyin awọn bẹbẹ loriṣiriṣi to ti gbe ṣe lere idaraya naa.
Amọṣa, lẹyin to gba idije Australian open ni ọdun 2017, eyi to mu ki iye ife ẹyẹ grandslam to ti gba o jẹ mẹtalelogun lo ti n lepa ati gba ẹyọkan sii ko lee jẹ mẹrinlelogun ti yoo si sọ ọ di elere idaraya Lawn tennis to da gba ami ẹyẹ Lawn tennis to pọ julọ ninu itan lagbaye.
Amọṣa, lati igba yii wa ni o ti n ba ijakulẹ pade.
Lẹni ọdun mejidinlogoji, ireti ọpọ nigba ti idije Australian open ti ọdun 2020 bẹrẹ ni pe ilakaka Serena Williams yoo so eso rere ki o to di pe o pade Wang Qiang ọmọ orilẹede China ni ipele kẹta idije naa.
Wang gbo ewuro soju Serena eleyi to jẹ ipele to ya ju ti Serena ti jabọ ni idije Lawn Tennis lati ọdun mẹrinla sẹyin ti o ti ja kulẹ ni ipele yii kan naa nigba to koju Daniela Hantuchova.
Williams ti kọkọ fẹyin Wang gbolẹ ni idije US open ni osu kẹsan ọdun to kọja ki Wang to wa gba ẹsan rẹ bayii













