Líìgì obìnrin: Gbèsè táwọn agbábọ́ọ́lù obìnrin jẹ pọ̀

Àwọn agbábọ́ọ̀lù obìnrin kan ń lé bọ́ọ̀lù

Oríṣun àwòrán, Nigeria women league board

Àkọlé àwòrán, Àjọ NWFL kéde gbèdéke ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹrin fún sísan gbèsè

Àjọ tó ń ṣe àmójútó idíje líìgì bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àwọn obìnrin lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, NWFL, ti pariwo síta pé, òun yóò sún idíje líìgì bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àwọn obìnrin síwájú pátápátá.

Ó ní kò sí ìdí méjì ju bí àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù obìnrin kan tó ń kópa nínú líìgì Nàìjíríà, kò ṣe tíì san owó tí wọ́n jẹ àjọ náà.

Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ti ṣíde líìgì bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá àwọn obìnrin lópin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, aláàmójútó àjọ náà, Ayọ̀ Abdulrahaman, ní ohun kan tó lè dènà sísún ìdíje náà síwájú ni kí àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó jẹ àjọ náà

ní gbèsè, yára tètè san owó tí wọ́n jẹ.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Àjọ ọ̀hún ní, gbèdéke ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹrin ọdún 2018, ni wọ́n fún àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó jẹ gbèsè náà láti fi san owó tí wọ́n jẹ.